ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 7/15 ojú ìwé 31
  • “Wọ́n Mọ Ohùn Rẹ̀”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Wọ́n Mọ Ohùn Rẹ̀”
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 7/15 ojú ìwé 31

“Wọ́n Mọ Ohùn Rẹ̀”

“OLUWA ni Olùṣọ́-Àgùtàn mi.” Ìwọ̀nyí ní àwọn ọ̀rọ̀ ìbẹ̀rẹ̀ Orin Dafidi 23. Ìwé Mímọ́ tún fi Jehofa Ọlọrun wé olùṣọ́-àgùtàn nínú àsọtẹ́lẹ̀ Isaiah, tí ó sọ pé: “Òun óò bọ́ ọ̀wọ́ ẹran rẹ̀ bí olùṣọ́-àgùtàn: yóò sì fi apá rẹ̀ kó àwọn ọ̀dọ́-àgùtàn, yóò sì kó wọn sí àyà rẹ̀, yóò sì rọra da àwọn tí ó lóyún.”​—⁠Isaiah 40:⁠11.

Bákan náà, Jesu Kristi ni a fiwé olùṣọ́-àgùtàn kan. Ó wí pé: “Èmi ni olùṣọ́-àgùtàn rere: olùṣọ́-àgùtàn rere fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn àgùtàn.” (Johannu 10:11) Jesu wí pé “àwọn àgùtàn sì gbọ́ ohùn [olùṣọ́-àgùtàn]: ó sì pe àwọn àgùtàn tirẹ̀ ní orúkọ, ó sì ṣe amọ̀nà wọn jáde.” Ó fikún un pé “àwọn àgùtàn sì ń tọ [olùṣọ́-àgùtàn] lẹ́yìn: nítorí tí wọ́n mọ ohùn rẹ̀. Wọn kò jẹ́ tọ àlejò lẹ́yìn, ṣùgbọ́n wọn a máa sá lọ́dọ̀ rẹ̀: nítorí tí wọn kò mọ ohùn àlejò.”​—⁠Johannu 10:​2-⁠5.

Jehofa Ọlọrun àti Ọmọkùnrin rẹ̀, Jesu Kristi, ti gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwòrán tí a gbé jáde nínú àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ tí a ti mẹ́nukàn wọ̀nyí. Wọ́n fi ọwọ́ jẹ̀lẹ́nkẹ́ àti ti ìtọ́jú onífẹ̀ẹ́ mú àwọn àgùtàn ìṣàpẹẹrẹ wọn. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí, àwọn ẹni-bí-àgùtàn nímọ̀lára jíjẹ́ ẹni tí a fẹ́ràn, tí kò séwu fún, tí a sì dáàbòbò.

Lọ́nà yíyẹwẹ́kú ipò-ìbátan yìí ni a fiwé ti àwọn àgùtàn gidi àti olùṣọ́-àgùtàn wọn. Lẹ́yìn lọ́hùn-⁠ún ní ọdún 1831, John Hartley kọ̀wé nípa àkíyèsí rẹ̀ lórí ọ̀ràn yìí. Ó ṣàkíyèsí pé ní Greece ó jẹ́ àṣà àwọn olùṣọ́-àgùtàn láti sọ àwọn àgùtàn wọn ní orúkọ. Nígbà tí a bá pè é lórúkọ, àgùtàn náà yóò dáhùnpadà sí ohùn olùṣọ́-àgùtàn náà. Ní nǹkan bí ọdún 51 lẹ́yìn náà, ní 1882, J. L. Porter ṣe àkíyèsí kan náà. Òun fúnraarẹ̀ fojúrí àwọn olùṣọ́-àgùtàn “tí irú ìkésíni híhangooro kan tí ó yàtọ̀ . . . ń ti ẹnu wọn jáde” èyí tí àwọn àgùtàn yóò dáhùnpadà sí nípa fífi tìgbọràn tìgbọràn tẹ̀lé àwọn olùṣọ́-àgùtàn náà. Ní ọdún kan náà yẹn William M. Thomson kọ̀wé nípa àwọn àṣeyẹ̀wò tí a ṣe ní àṣetúnṣe tí ó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn àgùtàn ni a lè kọ́ láti tẹ̀lé àwọn olùṣọ́-àgùtàn wọn àti láti mọ ohùn rẹ̀.

A ha ti ṣàkíyèsí ipò-ìbátan aláìlẹ́gbẹ́ yìí láàárín àwọn olùṣọ́-àgùtàn àti àwọn àgùtàn wọn ní àwọn àkókò lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí bí? Bẹ́ẹ̀ni. Nínú ìtẹ̀jáde ìwé National Geographic ti September 1993, olùdágbáléwu ará Australia kan Robyn Davidson kọ ohun tí ó tẹ̀lé e yìí nípa àwọn ará Rabari tí ń ṣiṣẹ́ olùṣọ́-àgùtàn ní àríwá ìwọ̀-oòrùn ilẹ̀ India pé: “Olùṣọ́-àgùtàn kọ̀ọ̀kan ní ọ̀nà ìgbàkésíni tí ó fi díẹ̀díẹ̀ yàtọ̀síra, ìyípadà nínú dídún ohùn. Wọ́n ní ìkésíni ti òwúrọ̀ láti gbéra, ìkésíni láti darí àwọn àgùtàn síbi tí omi wà, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ọkùnrin kọ̀ọ̀kan mọ àwọn àgùtàn tirẹ̀ bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn àgùtàn náà mọ olówó wọn, agbo àgùtàn tirẹ̀ ní pàtàkì yóò sì ya araarẹ̀ sọ́tọ̀ lára agbo tí ó túbọ̀ tóbi wọn yóò sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn ní òwúrọ̀.”

Láìsí iyèméjì, Jesu ṣàkíyèsí ohun tí àwọn arìnrìn-àjò mẹ́rin tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ mẹ́nukan tán yìí ṣàpèjúwe rẹ̀. Àwọn àkíyèsí tirẹ̀ fi ìjótìítọ́ kún àwọn àkàwé rẹ̀ nípa mímọ̀ tí àwọn àgùtàn mọ ohùn òun. Ìwọ ha wà lára àwọn àgùtàn Jesu bí? Ìwọ ha mọ ohùn rẹ̀ tí o sì ń fetísílẹ̀ sí i bí? Bí ìwọ bá mọ̀ tí o sì jẹ́wọ́ pé àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ jẹ́ òtítọ́ tí o sì ń ṣègbọràn sí àwọn àṣẹ rẹ̀ tí o sì ń tẹ̀lé ìdarí rẹ̀ nínú jíjọ́sìn Jehofa, nígbà náà ìwọ lè ní ìrírí bí Jehofa Ọlọrun àti Ọmọkùnrin rẹ̀, Jesu Kristi, ti ń fi tìfẹ́tìfẹ́ àti pẹ̀lú jẹ̀lẹ́ńkẹ́ ṣolùṣọ́-àgùtàn.​—⁠Johannu 15:⁠10.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́