Ọjọ́-Ọ̀la Wo Ni Ó Wà fún Àwọn Ọmọ Wa Kékeré?
ÌRỌ̀DẸ̀DẸ̀ ewu agbára átọ́míìkì—yálà nípasẹ̀ bọ́m̀bù àwọn akópayàbáni tàbí ìjàm̀bá láti ibi àwọn ilé-iṣẹ́ ìpèsè agbára átọ́míìkì—ń fì dùgbẹ̀dùgbẹ̀ lórí gbogbo ènìyàn. O lè máa bẹ̀rù ní pàtàkì nípa àwọn ọmọ kékeré, títíkan àwọn ọmọ tàbí àwọn ọmọ-ọmọ rẹ. Ó ti baninínújẹ́ tó láti mọ̀ pé ìrọ̀dẹ̀dẹ̀ ewu agbára átọ́míìkì ń fi ìlera àti ọjọ́-ọ̀la ọmọ èyíkéyìí sínú ewu.
Ṣùgbọ́n mọ́kàn. Ìdí wà fún ọ láti ní ìrètí tí ó dára nípa ọjọ́-ọ̀la àwọn ọmọdé. Ìpìlẹ̀ fún ìrètí sinmi lórí ọjọ́-ọ̀la tí ó sinmi lé ọwọ́ Ẹlẹ́dàá wa, kìí ṣe ìsapá ènìyàn láti dáàbòbo àwọn ọmọ wa kékeré.
Nígbà tí Jesu, Ọmọkùnrin Ọlọrun, kọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ní Àárín Gbùngbùn Ìlà-Oòrùn, ó ṣàníyàn nípa àwọn ọmọdé. (Marku 9:36, 37, 42; 10:13-16) Bibeli fihàn pé irú àníyàn kan náà ni a óò fihàn nígbà tí Ọlọrun bá fòpin sí ìrọ̀dẹ̀dẹ̀ ewu agbára átọ́míìkì níkẹyìn tí ó sì fìdí paradise kárí-ayé múlẹ̀. Àwọn ọmọ wa kékeré lè gbádùn ìyẹn, ìwọ náà sì lè ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.
Bí ìwọ yóò bá fẹ́ láti gba ìsọfúnni síwájú síi tàbí bí ìwọ yóò bá fẹ́ kí ẹnìkan kàn sí ọ láti ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́ pẹ̀lú rẹ, jọ̀wọ́ kọ̀wé sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, tàbí sí àdírẹ́sì tí ó ṣe wẹ́kú tí a tò sí ojú-ìwé 2.