Àkọlé tí Ó Ní Ìtumọ̀ Àrà-Ọ̀tọ̀
“IEHOVA SIT TIBI CUSTOS”
ÀWỌN ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí a kọ sára ògiri iwájú ilé kan tí a ti kọ́ láti ọ̀rúndún kẹtàdínlógún ní Celerina, níhà ìlà-oòrùn Switzerland, túmọ̀sí “Kí Jehofa jẹ́ aláàbò rẹ.” Ní agbègbè olókè yìí, kò ṣàjèjì láti rí i kí a gbẹ́ orúkọ Ọlọrun tàbí fi ọ̀dà kọ ọ́ sára àwọn ilé, ṣọ́ọ̀ṣì, àti ilé àlùfáà tí ó ti wà fún ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún. Báwo ní orúkọ náà Jehofa ṣe di èyí tí a mọ̀ bí-ẹni-mowó tóbẹ́ẹ̀?
Rhaetia ìgbàanì (tí ó ní nínú àwọn apá tí a ń pè ní gúúsù ìlà-oòrùn Germany, Austria, àti ìhà ìlà-oòrùn Switzerland nísinsìnyí) di ẹkùn-ìpínlẹ̀ Romu ní 15 B.C.E. Àwọn olùgbé ibẹ̀ bẹ̀rẹ̀ síí sọ èdè Romansh, èdè kan tí ó pilẹ̀ láti inú èdè Latin, tí ó wá gbèrú di àwọn èdè àdúgbò mélòókan tí a ṣì ń sọ ní àwọn apá ibìkan ní àfonífojì Alps ti Switzerland àti àríwá Italy.
Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, a túmọ̀ àwọn apákan nínú Bibeli sí èdè Romansh. Ẹ̀dà ìtẹ̀jáde kan, Biblia Pitschna, ní Orin Dafidi àti Ìwé Mímọ́ Kristian lédè Griki. Nínú Bibeli yìí, tí a tẹ̀jáde ní 1666, orúkọ náà Iehova farahàn lọ́pọ̀ ìgbà jálẹ̀ ìwé Psalmu. Níwọ̀n bí Bibeli ti jẹ́ olórí àkójọpọ̀ ẹ̀kọ́ fún kíkà nínú ilé, àwọn tí ń ka Biblia Pitschna di ojúlùmọ̀ pẹ̀lú orúkọ Ẹlẹ́dàá náà.
Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ìran tí ó tẹ̀lé e kò lọ́kàn ìfẹ́ mọ́ nínú ọ̀ràn tí ó bá jẹmọ́ Bibeli. Ọ̀pọ̀ kò bìkítà láti ṣèwádìí ohun tí ọ̀rọ̀ náà “Iehova” túmọ̀sí, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn àlùfáà kò sapá kankan láti ṣàlàyé rẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, ìkọ̀wé yìí di ohun ọ̀ṣọ́ lásán fún dídá sànmánì kan tí ó ti kọjá mọ̀.
Ní àwọn ẹ̀wádún díẹ̀ sẹ́yìn ìfòyeyéni pípẹtẹrí kan ti ń ṣẹlẹ̀. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti wá láti àwọn agbègbè onípẹ̀tẹ́lẹ̀, ní lílo àkókò ìsinmi ní àwọn àfonífojì rírẹwà wọ̀nyí tí wọ́n sì ń sapá gidigidi láti kọ́ àwọn olùgbé ibẹ̀ nípa Ọlọrun náà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jehofa. Àwọn Ẹlẹ́rìí kan tilẹ̀ ti fìdíkalẹ̀ sí àgbègbè yìí kí wọ́n baà lè lo àkókò púpọ̀ síi ní sísọ fún àwọn ènìyàn nípa àwọn ètè àgbàyanu Ẹlẹ́dàá fún ilẹ̀-ayé àti fún ènìyàn. Nípa báyìí, àkọlé èdè Romansh yìí ń gbé ìtumọ̀ titun rù bí àwọn ènìyàn wọ̀nyí ṣe ń kọ́ nípa Ọlọrun òtítọ́ náà, Jehofa.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]
IEHOVA PORTIO MEA: Jehofa ni ìpín mi.—Wo Orin Dafidi 119:57, “NW”