Ìgbàgbọ́ Onígboyà ti Àwọn Ará Wa ní Rwanda
NÍ ÌBẸ̀RẸ̀ ọdún 1994 ayé gbọ̀nrìrì bí ìròyìn nípa ìpakúpa rẹpẹtẹ ṣe ń rọ́wọlé láti orílẹ̀-èdè Africa náà Rwanda. Ogun abẹ́lé rírorò ti bẹ́sílẹ̀—òtéńté kùnrùngbùn tí ó ti gbárajọ fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún.
Bí wọ́n ti dojúkọ ìwólulẹ̀ pátápátá òfin àti àṣẹ, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tí wọ́n lé ní 2,000 ní Rwanda ni ó di dandan fún láti sá àsálà fún ẹ̀mí wọn. Nǹkan bíi 1,300 rí ibi ìsádi sí ibùdó àwọn olùwá-ibi-ìsádi ní Zaire àti Tanzania tí ó wà nítòsí, ṣùgbọ́n kò ṣeéṣe fún àwọn kan láti tètè sá àsálà. Ó dùn wá láti ròyìn pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 400 àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa—tọmọdé tàgbà, tí gbogbo wọn jẹ ará-ìlú—tí wọ́n dolóògbé nínú rògbòdìyàn tí ó kún fún ìkannú náà. Àwọn Kristian káàkiri àgbáyé ṣọ̀fọ̀ ìpàdánù àwọn olùpàwàtítọ́mọ́ onígboyà wọ̀nyí wọ́n sì rí ìtùnú gbà láti inú ìlérí àjíǹde tí ń bẹ nínú Bibeli.—Johannu 11:25.
Báwo ni nǹkan ti rí fún àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa tí wọ́n làájá ní Rwanda? A rán àwọn alàgbà láti àwọn orílẹ̀-èdè mélòókan láti kọ́kọ́ lọ ṣàyẹ̀wò bí ọ̀ràn ṣe rí. Ìròyìn kan fi tó wa létí pé àwọn ará ní Rwanda ti “fi ìparọ́rọ́ gidigidi àti ìgboyà” dojúkọ ipò náà. Fún àpẹẹrẹ, ọ̀kan lára àwọn ohun tí àwọn ará náà kọ́kọ́ béèrè fún ní àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Ìròyìn náà wá sí ìparí ní sísọ pé, ‘Ó dàbí ẹni pé rírí oúnjẹ tẹ̀mí gbà jẹ wọ́n lógún ju ìrànwọ́ ti ohun-ìní ti ara lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ní àìní gidigidi fún ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan.’ Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ipò àwọn nǹkan nínú àwọn ibùdó náà kò bódemu, ‘apá tí ó mọ́ tónítóní jùlọ níbẹ̀ ní àwọn ará wa ń gbé.’
Watch Tower Society ti pèsè owó fún ríra oúnjẹ, àwọn aṣọ ìbora, ẹ̀wù, bàtà, àti egbòogi. Àwọn ará wa ní France ṣètọrẹ ní yanturu, àti ní ìbẹ̀rẹ̀ June, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó tọ́ọ̀nù méjì àwọn ohun-èlò tí a kó ránṣẹ́ sí àwọn ará wa tí wọ́n ṣaláìní ní Rwanda.
Kò yanilẹ́nu pé, àwọn àyíká ìpò wọ̀nyí ti yọrísí ìjẹ́rìí tí ó jíire. A ti ru àwọn olùṣàkíyèsí sókè nítorí òtítọ́ náà pé àwọn ará wa ní Rwanda rí irú ìrànwọ́ àti ìtìlẹ́yìn bẹ́ẹ̀ gbà láti ọwọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ́ wọn, ó sì ti ṣeéṣe láti ṣàjọpín àwọn ìrànwọ́ wọ̀nyí pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Àwọn kan ti ṣàlàyé pé àwọn Ẹlẹ́rìí nìkan ni àwọn tí mẹ́ḿbà ìsìn wọn ti bẹ̀wò nínú ibùdó náà!
Ipò ọ̀ràn ìṣòro àwọn ará wa ní Rwanda ń rán wa létí pé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” wọ̀nyí, àwọn ènìyàn yóò jẹ́ “òǹrorò” àti “oníwà-ìpá.” (2 Timoteu 3:1-5; Today’s English Version) Bí ó sì tilẹ̀ jẹ́ pé Jehofa kò ṣèlérí ààbò kúrò lọ́wọ́ ewu nípa ti ara lọ́nà iṣẹ́ ìyanu fún àwọn ènìyàn rẹ̀, ó ṣèlérí láti dáàbòbo ipò tẹ̀mí àti ipò-ìbátan wọn pẹ̀lú rẹ̀, àti láti jí àwọn wọnnì tí wọ́n bá dolóògbé nísinsìnyí dìde, lákòókò ìṣàkóso Ẹlẹ́gbẹ̀rún Ọdún ti Kristi. (Orin Dafidi 91:1-10) Ǹjẹ́ kí àdúrà wa pé kí Jehofa mú àwọn ará wa ní Rwanda tí wọ́n ń la àkókò tí ń dánniwò yìí já dúró máa báa nìṣó láti jẹ́ èyí tí a ń gbà nítorí wọn.—Orin Dafidi 46:1.