Èéṣe tí Àwọn Ènìyàn Búburú Fi Ń Ní Aásìkí?
“NÍTORÍ kí ni ènìyàn búburú fi wà ní ààyè?” Jobu ọkùnrin olùṣòtítọ́ náà ni ó béèrè ìbéèrè yìí ní ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn, a sì ti sọ ọ́ léraléra lọ́pọ̀ ìgbà láti ọjọ́ rẹ̀ wá. Ó ṣeéṣe kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn tí ń gbé ní agbègbè ìpínlẹ̀ Yugoslavia àtijọ́ (bí irú obìnrin tí a fihàn lẹ́yìn ìwé wa) tí wọ́n ń ṣọ̀fọ̀ nítorí àwọn wọnnì tí wọ́n jìyà nínú ogun runlérùnnà kan ní in lọ́kàn. Èéṣe tí àwọn ènìyàn búburú fi ń làájá tí wọ́n sì ń ní aásìkí? Gẹ́gẹ́ bí Jobu ti ṣàkíyèsí, lọ́pọ̀ ìgbà “ilé wọn wà láìní ewu, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀pá-ìna Ọlọrun kò sí lára wọn.”—Jobu 21:7, 9.
Èyí ha túmọ̀sí pé kò sí èrè kankan nínú ṣíṣiṣẹ́sin Ọlọrun, nínífẹ̀ẹ́ aládùúgbò ẹni, àti fífàsẹ́yìn kúrò nínú ṣíṣe ohun tí kò tọ́? Kí a má rí i! Bibeli fún wa ní ojú-ìwòye tí ó tọ̀nà nígbà tí ó sọ pé: “Máṣe gbìyànjú láti ta àwọn tí ń hùwà ibi yọ tàbí ṣe àfarawé àwọn tí ń ṣe ohun tí kò tọ́. Nítorí bíi ewéko ní wọn yóò ṣe rọ, tí wọn yóò sì joro bí ewéko ìgbà òjò. Gbẹ́kẹ̀lé OLUWA kí o sì máa ṣe rere.”—Orin Dafidi 37:1-3, The New English Bible.
Bẹ́ẹ̀ni, aásìkí tí ó hàn gbangba pé àwọn ènìyàn búburú ni tí a ń rí báyìí wulẹ̀ jẹ́ fún ìgbà díẹ̀. Níti gàsíkíyá, ìgbésí-ayé wọn kúrú jọjọ, nígbà tí ó sì jẹ́ pé àwọn wọnnì tí wọ́n ń ṣiṣẹ́sin Ọlọrun ní ìrètí ológo kan fún ọjọ́-ọ̀la. Láìpẹ́, ìlérí Ọlọrun yóò ní ìmúṣẹ pé: “[Ọlọrun] yoo sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yoo sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yoo sí ọ̀fọ̀ tabi igbe ẹkún tabi ìrora mọ́. Awọn ohun atijọ ti kọjá lọ.” (Ìṣípayá 21:4, NW) Kìkì àwọn olódodo, kìí ṣe àwọn ènìyàn búburú, ní yóò rí àkókò yẹn. Ẹ sì wo bí ó ti jẹ́ ìṣírí tó láti súnmọ́ Ọlọrun kí a sì kọ́ láti ṣe ìfẹ́-inú rẹ̀, bí ó ti wù kí àwọn tí wọ́n yí wa ká jẹ́ ènìyàn búburú tó!
Bí ìwọ yóò bá fẹ́ láti gba ìsọfúnni síwájú síi, tàbí bí ìwọ yóò bá fẹ́ kí ẹnìkan máa darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú-ilé lọ́fẹ̀ẹ́ pẹ̀lú rẹ, jọ̀wọ́ kọ̀wé sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, tàbí sí àdírẹ́sì tí ó ṣe wẹ́kú tí a tò sí ojú-ìwé 2.