New World Translation Wú Ọ̀mọ̀wé Akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan Lórí
GẸ́GẸ́ bí ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan nínú èdè Griki ìgbàanì Dókítà Rijkel ten Kate ti sọ, Bibeli lédè Dutch kùnà láti túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ kan lọ́nà pípéye. Fún àpẹẹrẹ, ní Luku orí 2, a rí bí a ṣe lo àwọn ọ̀rọ Griki mẹ́ta tí ó yàtọ̀ síra (breʹphos, pai·diʹon, àti pais) láti ṣàpèjúwe ìpele ìdàgbàsókè Jesu ní ṣísẹ̀ntẹ̀lé. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní ìtumọ̀ díẹ̀ tí ó yàtọ̀ síra. Bí ó ti wù kí ó rí, nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ Bibeli, méjì tàbí mẹ́ta nínú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni a túmọ̀ ní ṣákálá sí “ọmọdé.” Kí ni ìtumọ̀ tí ó tọ̀nà?
Dókítà ten Kate ṣàlàyé pé ní ẹsẹ 12 ọ̀rọ̀ Griki náà breʹphos, túmọ̀ sí “ìkókó, tàbí ọmọdé jòjòló.” Pai·diʹon, tí a lò ní ẹsẹ 27, túmọ̀ sí “ọmọdékùnrin kékeré tàbí ọmọ kékeré,” àti pais, tí a rí ní ẹsẹ̀ 43, ni ó yẹ kí a túmọ̀ sí “ọmọdékùnrin.” Dókítà ten Kate nínú ìtẹ̀jáde Bijbel en Wetenschap (Bibeli àti Ìmọ̀-Ìjìnlẹ̀) ti March 1993 kọ̀wé pé: “Gẹ́gẹ́ bí ibi tí òye mi mọ, kò tí ì sí ìtumọ̀ èdè Dutch kan tí ó túmọ̀ èyí lọ́nà tí ó pegedé, ìyẹn ni pé, kí ó wà ní ìbámu pátápátá pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ẹsẹ̀ ìwé ìpilẹ̀ṣẹ̀.”
Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, a fi New World Translation of the Holy Scriptures han Dókítà ten Kate, èyí tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní èdè 12, títíkan èdè Dutch. Kí ni ìhùwàpadà rẹ̀? Ó wí pé: “Ó yà mí lẹ́nu gidigidi, pé Bibeli kan wà ní èdè Dutch tí a ti gbé ìlò yíyàtọ̀ síra ti àwọn ọ̀rọ̀ Griki mẹ́ta náà breʹphos, pai·diʹon, àti pais yẹ̀wò lọ́nà tí ó tọ́.” Bibeli New World Translation ha túmọ̀ àwọn ẹsẹ wọ̀nyí ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ẹsẹ̀ ìwé Griki ìpilẹ̀ṣẹ̀ bí? Dókítà ten Kate dáhùn pé: “Rẹ́gí ló ṣe.”