‘Bí Irin Ti Í Pọ́n Irin’
BÍ Ọ̀RÚNDÚN kẹta C.E., ṣe ń parí lọ, ọ̀dọ́mọkùnrin onítara kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Anthony, tí a ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bíi “Kristian onísìn Copt,” kúrò láàárín aráyé, ó sì lo ogun ọdún ní àdádó nínú aṣálẹ̀. Èé ti rí? Ó rò pé, ọ̀nà tí ó dára jù lọ nìyẹn fún òun láti lè sin Ọlọrun. Òun ni ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé ti Kristẹndọmu àkọ́kọ́, tí ó nípa ìdarí púpọ̀ lórí ẹ̀dá.
Lónìí, ìwọ̀nba díẹ̀ ni ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé tí Kristẹndọmu ní. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ń wá ọ̀nà mìíràn láti wà ní àdádó. Wọ́n ń kọ̀ láti bá àwọn mìíràn sọ̀rọ̀ nípa ìsìn wọn, ní ríronú pé irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ lè jálẹ̀ sí àìfohùnṣọ̀kan àti ìjà. Ní pàtàkì, ìjọsìn wọn ní ṣíṣe rere sí aládùúgbò wọn nínú.
Lóòótọ́, ṣíṣe rere sí aládùúgbò ẹni jẹ́ apá kan ìsìn tòótọ́, ṣùgbọ́n ó ń béèrè jù bẹ́ẹ̀ lọ. Òwe ìgbàanì kan sọ pé: “Irin a máa pọ́n irin: bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin í pọ́n ojú ọ̀rẹ́ rẹ̀.” (Owe 27:17) Òkodoro òtítọ́ náà ni pé, Bibeli fún àwọn Kristian níṣìírí láti pàdé pọ̀, kì í ṣe láti ya ara wọn sọ́tọ̀ ní àdádó pátápátá kúrò nínú ayé tàbí lọ́dọ̀ àwọn Kristian mìíràn. (Johannu 17:14, 15) Ó wí pé: “Ẹ . . . jẹ́ kí a gba ti ara wa rò lẹ́nìkínní kejì lati ru ara wa lọ́kàn sókè sí ìfẹ́ ati sí awọn iṣẹ́ àtàtà, kí a má máa ṣá ìpéjọpọ̀ ara wa tì.” (Heberu 10:24, 25) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yẹn. Lọ́pọ̀ ìgbà láàárín ọ̀sẹ̀, wọ́n ń pàdé pọ̀ láti ‘pọ́n ojú ara wọn lẹ́nìkínní kejì,’ ní gbígbé ìgbàgbọ́ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn ró. Wọ́n rí i pé jíjíròrò Bibeli láìṣàbòsí kì í yọrí sí ìjà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ń yọrí sí ìṣọ̀kan àti àlàáfíà. Ó jẹ́ apá pàtàkì kan nínú ìjọsìn tòótọ́.