Ìgbàgbọ́ Sún un Láti Gbégbèésẹ̀
NÍGBÀ tí Jehofa pàṣẹ fún Mose láti ṣáájú orílẹ̀-èdè Israeli kúrò nínú oko ẹrú àwọn ará Egipti, lákọ̀ọ́kọ́, Mose bẹ̀bẹ̀ pé kí a yọ̀ọ̀da òun, ní sísọ pé: “Oluwa, èmi kì í ṣe ẹni ọ̀rọ̀ sísọ nígbà àtijọ́ wá, tàbí láti ìgbà tí o ti ń bá ìránṣẹ́ rẹ sọ̀rọ̀: ṣùgbọ́n olóhùn wúwo ni mí, àti aláhọ́n wúwo.” (Eksodu 4:10) Bẹ́ẹ̀ ni, Mose nímọ̀lára àìtóótun fún irú iṣẹ́ àyànfúnni bàǹtàbanta bẹ́ẹ̀.
Bákan náà lónìí, nígbà míràn, ọ̀pọ̀ ìránṣẹ́ Jehofa máa ń nímọ̀lára àìtóótun láti ṣe iṣẹ́ tí a yàn fún wọn. Fún àpẹẹrẹ, Kristian alábòójútó kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Theodore ròyìn pé: “Nínú gbogbo ohun tí Jehofa ní kí n ṣe, iṣẹ́ ìsìn pápá ni ó le jù. Nígbà tí mo wà ní kékeré, n óò sáré rìn lọ sí ẹnu ọ̀nà, n óò díbọ́n bíi pé mo kan ilẹ̀kùn, n óò sì rìn kánmọ́kánmọ́ kúrò níbẹ̀, pẹ̀lú ìrètí pé ẹni kẹ́ni kò gbọ́ tàbí rí mi. Bí mo ti ń dàgbà, mo dẹ́kun ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n èrò àti lọ láti ilé dé ilé máa ń mú mi ṣàárẹ̀. Àní títí di ìsinsìnyí pàápàá, ojora máa ń mù mi ṣáájú jíjáde lọ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́, ṣùgbọ́n mo ṣì máa ń lọ.”
Kí ni ó mú kí Mose àti àwọn Ẹlẹ́rìí òde òní bíi Theodore lè kápá irú ìbẹ̀rù bẹ́ẹ̀? Bibeli dáhùn pé: “Nipa ìgbàgbọ́ ni ó [Mose] fi Egipti sílẹ̀, . . . nitori tí ó ń bá a lọ ní fífẹsẹ̀múlẹ̀ ṣinṣin bí ẹni tí ń rí Ẹni naa tí a kò lè rí.”—Heberu 11:27.
Ní tòótọ́, nípa lílo ìgbàgbọ́ nínú Jehofa, ó ṣeé ṣe fún Mose láti borí ìmọ̀lára àìtóótun rẹ̀, kí ó sì ṣe iṣẹ́ tí a yàn fún un gẹ́gẹ́ bí onídàájọ́, wòlíì, aṣáájú orílẹ̀-èdè, alárinà májẹ̀mú Òfin, aláṣẹ, òpìtàn, àti akọ̀wé Bibeli.
Bákan náà, nígbà tí a bá ní ìgbàgbọ́ bíi Mose, a óò rìn bí ẹni tí ‘ń rí Ẹni náà tí a kò lè rí.’ Irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ ń gbé ìgboyà ró, ní ríràn wá lọ́wọ́ láti gbé àwọn ẹrù iṣẹ́ Kristian wa—àní nígbà tí a bá nímọ̀lára àìtóótun pàápàá.