ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 5/1 ojú ìwé 30
  • Agbára Ayínipadà Tí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun Ní

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Agbára Ayínipadà Tí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun Ní
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 5/1 ojú ìwé 30

Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn

Agbára Ayínipadà Tí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun Ní

Ó FẸNU ara rẹ̀ sọ pé, tẹ́lẹ̀ rí òún jẹ́ “asọ̀rọ̀ òdì ati onínúnibíni ati aláfojúdi.” (1 Timoteu 1:13) Ṣùgbọ́n ó yí padà! Bí aposteli Paulu ṣe yí padà yani lẹ́nu tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi lè polongo lẹ́yìn náà pé: “Ẹ di aláfarawé mi, àní gẹ́gẹ́ bí emi ti di ti Kristi.”—1 Korinti 11:1.

Lónìí, ọgọ́rọ̀ọ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn olùfitọkàntọkàn jọ́sìn tí wọ́n wà káàkiri àgbáyé ń ṣe irú ìyípadà bẹ́ẹ̀. Kí ni ó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀? Wọ́n ń gba ìmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sínú, wọ́n sì ń fi sílò nínú ìgbésí ayé wọn. Ìrírí tí ó tẹ̀ lé e tẹnu mọ́ agbára ayínipadà tí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ní.

Ní Slovenia, tọkọtaya àgbàlagbà kan ń dá gbé ní ẹ̀yin òde abúlé kan. Jože, tí ó jẹ́ ọkọ, jẹ́ ẹni nǹkan bí 60 ọdún, ó sì ní ìṣòro ìmukúmu gidigidi. Síbẹ̀, ó tọ́jú aya rẹ̀, Ljudmila, tí ara rẹ̀ kò dá. Ní ọjọ́ kan, àwọn méjì tí wọ́n jẹ́ olùpòkìkí Ìjọba tọ Jože wá. Ó ké sí àwọn Ẹlẹ́rìí náà wọnú ilé rẹ̀, níbi tí wọ́n ti bá aya rẹ̀. Nígbà tí ó gbọ́ ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà, omijé ìdùnnú ṣàn pòròpòrò ní ojú Ljudmila. Jože pẹ̀lú gbádùn ohun tí ó gbọ́, ó sì béèrè ọ̀pọ̀ ìbéèrè. Lẹ́yìn fífi àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli mélòó kan sílẹ̀ fún tọkọtaya náà, àwọn Ẹlẹ́rìí náà bá tiwọn lọ.

Oṣù kan lẹ́yìn náà, ó ṣeé ṣe fún àwọn Ẹlẹ́rìí náà láti padà wá, wọ́n sì ṣàkíyèsí pé ìwé náà, Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye, wà lórí tábìlì. Nígbà tí wọ́n béèrè bí ó ṣe dọ́wọ́ rẹ̀, Jože wí pé: “Mo rí ibi tí a ti polówó rẹ̀ ní ojú ewé tí ó kẹ́yìn ọ̀kan nínú àwọn ìwé ìròyìn tí ẹ fi sílẹ̀ fún mi. Mo sì kọ lẹ́tà sí ọ́fíìsì yín ní Zagreb, mò sì béèrè fún ìwé náà.” Nítorí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀, wọ́n pè é síbi Ìṣe Ìrántí ikú Kristi tí yóò tẹ̀ lé e, tí wọn yóò ṣe ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ẹ wo bí inú àwọn Ẹlẹ́rìí náà ṣe dùn tó pé ó wá!

Láìpẹ́, wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, ó sì tẹ̀ síwájú dáadáa. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí wọ́n fi han Jože láti inú Bibeli pé “ìwọ kò gbọdọ̀ ya ère fún ara rẹ, tàbí . . . tẹ orí ara rẹ ba fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ sìn wọ́n,” lójú ẹsẹ̀ ni ó kó gbogbo ère ìsìn tí ń bẹ nínú ilé rẹ̀ jọ, títí kan àwọn àwòrán ìsìn, ó sì kó wọn dànù.—Eksodu 20:4, 5.

A pòùngbẹ òtítọ́ nípa tẹ̀mí tí ń gbẹ Jože. Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé, òùngbẹ mìíràn ṣì ń gbẹ ẹ́. Fún nǹkan bí ọdún 18, ó ti ń mu lítà wáìnì méje lójoojúmọ́. Nítorí ìṣòro ọtí mímu tí ó ní, kì í fi àfiyèsí púpọ̀ sí ìrísí ara rẹ̀. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí ó kọ́ nípa ojú tí Ọlọrun fi ń wo mímu ọtí ní àmujù, ó pinnu láti yí padà.

Ó sakun láti borí ìṣòro ọtí mímu rẹ̀ díẹ̀díẹ̀, ní ṣíṣàkọsílẹ̀ iye tí òún ń mu lójúmọ́. Kò pẹ́ kò jìnnà, kò sinrú fún wáìnì mọ́. Bí ó ṣe ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli rẹ̀ lọ, ó tún kọ́ pé, a béèrè pé kí àwọn Kristian tòótọ́ jẹ́ onímọ̀ọ́tótó. Nítorí náà, ó fún àwọn Ẹlẹ́rìí náà ní owó, ó sì wí pé: “Toò, ẹ lọ ra irú ẹ̀wù tí mo nílò kí n baà lè ṣeé wò ní àwọn ìpàdé Kristian àti nínú iṣẹ́ ìsìn pápá!” Àwọn Ẹlẹ́rìí náà kó àwọ̀tẹ́lẹ̀, ìbọ̀sẹ̀, bàtà, ṣẹ́ẹ̀tì, kóòtù, táì, àti àpò ìfàlọ́wọ́ wá.

Lẹ́yìn kíkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli fún ọdún kan, Jože àti Ljudmila tóótun láti bá àwọn Ẹlẹ́rìí jáde fún iṣẹ́ ìwàásù láti ilé dé ilé. Oṣù mẹ́ta lẹ́yìn náà, wọ́n fi àpẹẹrẹ ìyàsímímọ́ wọn hàn sí Ọlọrun nípa ṣíṣe ìrìbọmi ní àpéjọpọ̀ àgbègbè ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Láìka ọjọ́ ogbó àti ìlera tí kò dára tó sí, Jože ń nípìn-ín déédéé nínú wíwàásù ìhìn rere náà, lẹ́yìn náà, títí tí ó fi kú ní May 1995, ó fi ìṣòtítọ́ ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú ìjọ. Èso rere tí ìgbésí ayé ọkùnrin onírẹ̀lẹ̀ yìí àti aya rẹ̀ mú jáde jẹ́rìí sí agbára ayínipadà tí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ní!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́