ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 7/15 ojú ìwé 30
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ‘Kí Ni Yóò Ṣe Àmì Wíwàníhìn-Ín Rẹ?’
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • “Sọ Fún Wa, Nígbà Wo Ni Nǹkan Wọ̀nyí Yóò Ṣẹ?”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Kí Ni Bíbélì Sọ Tẹ́lẹ̀ Nípa Àwọn Ìmìtìtì Ilẹ̀ Tó Lágbára?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Bí Ilẹ̀ Sísẹ̀ Àti Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì Ṣe Kàn Ọ́
    Jí!—2002
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 7/15 ojú ìwé 30

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Mo mọ̀ pé a máa ń lo ọ̀rọ Gíríìkì náà, “toʹte” (nígbà náà), láti nasẹ̀ ọ̀rọ̀ tí ó tẹ̀ lé e. Nítorí náà èé ṣe tí Mátíù 24:9 fi kà pé: “Nígbà náà [“toʹte”] ni àwọn ènìyàn yóò fà yín lé ìpọ́njú lọ́wọ́,” nígbà tí àkọsílẹ̀ tí ó bá a mu nínú Lúùkù 21:12 sọ pé: “Ṣùgbọ́n ṣáájú gbogbo nǹkan wọ̀nyí àwọn ènìyàn yóò gbé ọwọ́ wọn lé yín wọn yóò sì ṣe inúnibíni sí yín”?

Òtítọ́ ni pé a lè lo toʹte láti nasẹ̀ ohun kan tí yóò tẹ̀ lé e, ohun kan tí ó so kọ́ra, kí a sọ ọ́ lọ́nà bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n kò yẹ kí a rò pé ọ̀nà yìí nìkan ṣoṣo ní Bíbélì gbà lo ọ̀rọ̀ náà.

Ìwé náà, A Greek-English Lexicon of the New Testament and Other Early Christian Literature, láti ọwọ́ Bauer, Arndt, àti Gingrich, fi hàn pé ọ̀rọ̀ náà, toʹte, ni a lò ní ìtumọ̀ méjì pàtàkì nínú Ìwé Mímọ́.

Ọ̀kan ni “ní àkókò náà.” Èyí lè jẹ́ “nígbà náà ti ìṣẹ̀lẹ̀ àtẹ̀yìnwá.” A fúnni ní àpẹẹrẹ kan nínú Mátíù 2:17 pé: “Nígbà náà ni a mú èyíinì ṣẹ tí a sọ nípasẹ̀ Jeremáyà wòlíì.” Èyí kò tọ́ka sí ohun kan tí ó ṣẹlẹ̀ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé, ṣùgbọ́n ó ń tọ́ka sí àkókò kan pàtó látẹ̀yìnwá, ní àkókò náà. Lọ́nà kan náà, a tún lè lo toʹte fún “nígbà náà ti ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ ọ̀[la].” A rí àpẹẹrẹ kan ní Kọ́ríńtì Kìíní 13:12 tí ó sọ pé: “Nítorí pé nísinsìnyí àwa ń ríran ní ìlà àwòrán fírífírí nípasẹ̀ jígí mẹ́táàlì, ṣùgbọ́n nígbà náà yóò jẹ́ ní ojúkojú. Nísinsìnyí mo mọ̀ lápá kan, ṣùgbọ́n nígbà náà èmi yóò mọ̀ lọ́nà pípéye àní gẹ́gẹ́ bí a ti mọ̀ mí lọ́nà pípéye.” Pọ́ọ̀lù lo toʹte níhìn-ín ní ìtumọ̀ ti ‘àkókò kan ní ọjọ́ ọ̀la.’

Gẹ́gẹ́ bí ìwé atúmọ̀ èdè yìí ti sọ, ọ̀nà míràn tí a ń gbà lo toʹte ni “láti nasẹ̀ àkókò tí nǹkan ṣẹlẹ̀ tẹ̀ léra.” Ìwé àtúmọ̀ èdè yìí fúnni ní ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ tí a rí nínú àkọsílẹ̀ mẹ́ta lórí ìdáhùn Jésù sí ìbéèrè àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ nípa wíwà níhìn-ín rẹ̀.a Gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ lílo toʹte “láti nasẹ̀ àkókò tí nǹkan ṣẹlẹ̀ tẹ̀ léra,” ìwé atúmọ̀ èdè náà yan Mátíù 24:10, 14, 16, 30; Máàkù 13:14, 21; àti Lúùkù 21:20, 27. Gbígbé àyíká ọ̀rọ̀ yìí yẹ̀ wò fi ìdí tí a fi ń ní òye tí ó tọ́ nípa ohun tí ń ṣẹlẹ̀ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé hàn. Èyí sì ṣèrànwọ́ láti lóye àsọtẹ́lẹ̀ Jésù tí ó ní bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ ọ̀la yóò ṣe bẹ̀rẹ̀ nínú.

Bí ó ti wù kí ó rí, kò yẹ kí a parí èrò sí pé gbogbo ibi tí toʹte ti fara hàn nínú àwọn àkọsílẹ̀ wọ̀nyí gbọ́dọ̀ nasẹ̀ àkókò tí àwọn nǹkan ṣẹlẹ̀ tẹ̀ léra. Fún àpẹẹrẹ, ní Mátíù 24:7, 8, a kà pé Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè àti pé àìtó oúnjẹ àti ìmìtìtì ilẹ̀ yóò wà. Ẹsẹ 9 ń bá a nìṣó pé: “Nígbà náà ni àwọn ènìyàn yóò fà yín lé ìpọ́njú lọ́wọ́ wọn yóò sì pa yín, ẹ̀yin yóò sì jẹ́ ohun ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ní tìtorí orúkọ mi.” Yóò ha lọ́gbọ́n nínú láti lóye pé ogun, àìtó oúnjẹ, àti ìmìtìtì ilẹ̀ tí a sọ tẹ́lẹ̀ látòkè délẹ̀ gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀, bóyá kí ó sì dáwọ́ dúró, kí inúnibíni tó bẹ̀rẹ̀ bí?

Ìyẹn kò bọ́gbọ́n mu, bẹ́ẹ̀ sì ni kó bá ohun tí a mọ̀ nípa ìmúṣẹ ọ̀rúndún kìíní mu. Àkọsílẹ̀ inú ìwé Ìṣe ṣí i payá pé, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ kété lẹ́yìn tí àwọn mẹ́ḿbà ìjọ Kristẹni bẹ̀rẹ̀ sí wàásù, ni wọ́n nírìírí àtakò líle koko. (Ìṣe 4:5-21; 5:17-40) Dájúdájú àwa kò lè sọ pé ogun, ìyàn, àti ìmìtìtì ilẹ̀ tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ látòkè délẹ̀ ṣẹlẹ̀ ṣáájú inúnibíni ìjímìjí yẹn. Ní òdì kejì, àtakò yẹn wáyé “ṣáájú” ọ̀pọ̀ nǹkan mìíràn tí a sọ tẹ́lẹ̀, èyí tí ó wà ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí Lúùkù gbà gbé ọ̀rọ̀ náà kalẹ̀ pé: “Ṣùgbọ́n ṣáájú gbogbo nǹkan wọ̀nyí àwọn ènìyàn yóò gbé ọwọ́ wọn lé yín wọn yóò sì ṣe inúnibíni sí yín.” (Lúùkù 21:12) Ìyẹn yóò fi hàn pé ní Mátíù 24:9, a lo toʹte lọ́nà tí ó túbọ̀ túmọ̀ sí “ní àkókò náà.” Ní sáà ogun, ìyàn, àti ìmìtìtì ilẹ̀, tàbí ní àkókò náà, a óò ṣe inúnibíni sí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A gbé àwọn àkọsílẹ̀ bíbára mu wọ̀nyí nínú Mátíù, Máàkù, àti Lúùkù jáde nínú òpó ìlà ní ojú ìwé 14 àti 15 ti Ilé-Ìṣọ́nà, February 15, 1994. Àwọn ibi tí a ti lo toʹte, bíi “nígbà náà,” wà ní lẹ́tà gàdàgbà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́