“Àlá Kọ́ Ni Mò Ń Lá Ṣá, Àbí?”
Ìròyìn tí ó tẹ̀ lé e yìí wá láti Màláwì, nípa ọ̀kan nínú àwọn Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Onídùnnú-Ayọ̀ Olùyìn” ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí ó jẹ́ mánigbàgbé, tí a ṣe níbẹ̀ ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn 1995.
“NÍ ÒPÓPÓNÀ ńlá kan, tí ó wà ní nǹkan bí ìlàjì ọ̀nà sí èbúté ìwọ̀ oòrùn Adágún Màláwì, a ri àkọlé kan mọ́lẹ̀ síbẹ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́ nínú ọdún 29. Ó kà pé, ‘Àpéjọpọ̀ Àgbègbè Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.’
“A gbé ọkọ̀ akẹ́rù gàgàrà kan sẹ́gbẹ̀ẹ́ àkọlé náà, àwọn àyànṣaṣojú tí ó lé ní 200 láti ìlú Mzuzu, sì ń sọ̀kalẹ̀ láti ẹ̀yìn rẹ̀. Wọ́n kó ọ̀pọ̀ aṣọ, kùbúsù, ìkòkò, korobá, oúnjẹ, igi ìdáná, àti Bíbélì wá láti dara pọ̀ mọ́ nǹkan bí 3,000 àwọn arákùnrin àti arábìnrin wọn láti ọ̀gangan mìíràn.
“Bí a ṣe ń kí àwọn ará tí ń sọ̀kalẹ̀ láti inú ọkọ̀ akẹ́rù náà káàbọ̀, George Chikako, ẹni ọdún 63 dé, ó ń ti kẹ̀kẹ́ ológeere rẹ̀ gba inú iyanrìn bọ̀, lẹ́yìn tí ó ti gùn ún fún ọjọ́ méjì láti Nkhotakota. Jálẹ̀ àwọn ọdún wọ̀nyí, Arákùnrin Chikako ti ṣẹ̀wọ̀n nígbà mẹ́rin gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí kíkọ̀ tí ó kọ̀ láti fi ìlànà Bíbélì báni dọ́rẹ̀ẹ́. Ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ kan kú nítorí lílù tí wọ́n lù ú nígbà tí ó wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n. Arákùnrin Chikako béèrè pé: ‘Àlá kọ́ ni mò ń lá ṣá, àbí? Ojúmọmọ ni a ń ṣe àpéjọpọ̀ yìí kẹ̀, àwọn ènìyàn wọ̀nyí sì ń kọrin Ìjọba sókè! Fún ọ̀pọ̀ ọdún, inú òkùnkùn alẹ̀ ni a máa ń pàdé, tí a ń kọrin Ìjọba wúyẹ́wúyẹ́, tí a sì ń fọwọ́ ra ọwọ́ láti pàtẹ́wọ́. Wàyí o, a ń pàdé ní gbangba, ẹnu sì ya àwọn ènìyàn láti rí i pé a pọ̀ tó bẹ́ẹ̀, níwọ̀n bí wọ́n ti rò pé a kéré níye púpọ̀púpọ̀!’
“Ewéko ni a fi ṣe ọgbà yí ọ̀gangan àpéjọpọ̀ náà ká, a sì fi esùsú bò ó gátagàta láti pèsè ibòji. A kọ́ àwọn ahéré oníkoríko àti àwọn ilé ìbùwọ̀ gbalasa láti fi àwọn àyànṣaṣojú wọ̀ sí. Atẹ́gùn alẹ̀ kún fún ìró àwọn ohùn atunilára tí ó dùn ún gbọ́, tí ìbẹ̀rù inúnibíni kò pa lẹ́nu mọ́, mọ́.
“Ẹ wo bí ó ti bá a mu wẹ́kú tó pé, a pe ẹṣin ọ̀rọ̀ àpéjọpọ̀ náà ní ‘Àwọn Onídùnnú-Ayọ̀ Olùyìn’!”
[Credit Line]
Mountain High Maps® Copyright © 1995 Digital Wisdom, Inc.