ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 8/15 ojú ìwé 32
  • Àwọn Ògbóǹtagí Ṣàgbéyẹ̀wò Àwọn Àfidípò Ẹ̀jẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ògbóǹtagí Ṣàgbéyẹ̀wò Àwọn Àfidípò Ẹ̀jẹ̀
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 8/15 ojú ìwé 32

Àwọn Ògbóǹtagí Ṣàgbéyẹ̀wò Àwọn Àfidípò Ẹ̀jẹ̀

NǸKAN bí 200 ògbóǹtagí láti agbègbè United States pàdé ní Cleveland, Ohio, ní Saturday, October 7, 1995, láti jíròrò ọ̀ràn tí ó túbọ̀ ń di ohun tí àwọn onímọ̀ nípa ìṣègùn ń ní ìfẹ́ ọkàn sí: oògùn àti iṣẹ́ abẹ aláìlo ẹ̀jẹ̀.

Wọ́n jíròrò ọ̀pọ̀ àyíká ipò tí ń peni níjà. Fún àpẹẹrẹ, bí aláìsàn kán bá ní àrùn àìtó ẹ̀jẹ̀ tí ó le koko ńkọ́? Báwo ni a ṣe lè tọ́jú ọmọ ọwọ́ tí a bí ní kògbókògbó gan-an láìlo ẹ̀jẹ̀? A ha lè ṣe iṣẹ́ abẹ ọkàn láṣeyọrí láìsí ìfàjẹ̀sínilára bí? Ó dùn mọ́ni nínú pé, iṣẹ́ abẹ aláìlo ẹ̀jẹ̀—ọgbọ́n ìṣiṣẹ́ tí a sábà ń lò, tí ń ṣèrànwọ́ fún ara láti fúnra rẹ̀ gbé ìpèsè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ró—ni a ti lò ní gbogbo àwọn ipò yìí pẹ̀lú àbájáde rere.a

Èé ṣe tí a fi ń fẹ́ àfidípò fún fífa ẹ̀jẹ̀ síni lára? Sharon Vernon, olùdarí Ibùdó fún Oògùn Aláìlo Ẹ̀jẹ̀ àti Iṣẹ́ Abẹ ní St. Vincent Charity Hospital ní Cleveland sọ pé: “A ti rí i pé fífa ẹ̀jẹ̀ síni lára sábà máa ń kó àrùn ranni, ní pàtàkì àrùn mẹ́dọ̀wú.” Ó tẹ̀ síwájú pé: “Àní nígbà tí ẹ̀jẹ̀ kò bá kéèràn ranni pàápàá, ó lè mú kí agbára ìdènà àrùn aláìsàn náà dín kù.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti dín títan àrùn AIDS kálẹ̀ kù nípasẹ̀ àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀, ọ̀pọ̀ àrùn ṣì kù síbẹ̀ tí irú àyẹ̀wò bẹ́ẹ̀ kò lè rí. Láìkò sì ka àìní náà fún ìmúrasílẹ̀ púpọ̀ tí ó ní sí, iṣẹ́ abẹ aláìlo ẹ̀jẹ̀ ń dín àwọn ilé ìwòsàn lówó kù, níwọ̀n bí ó ti ń mú àwọn ìṣòro tí ó jẹ mọ́ òfin, tí ó lè jẹ yọ nígbà tí àwọn aláìsàn bá gba ẹ̀jẹ̀ tí ó ti di alábàwọ́n, kúrò.

Lójú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìdí ṣíṣe pàtàkì jù lọ kan wà fún yíyẹra fún gbígba ẹ̀jẹ̀ sára: Òfin Ọlọ́run kà á léèwọ̀. (Ìṣe 15:29) Síbẹ̀, wọ́n ń fẹ́ láti gba ìtọ́jú ìṣègùn tí ó dára jù lọ, tí wọ́n bá lè rí gbà. Nípa báyìí, wọ́n ti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn dókítà, tí wọ́n ń ṣagbátẹrù ìwádìí nípa ìtọ́jú ìṣègùn aláìlo ẹ̀jẹ̀. Kì í ṣe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan ni irú ìtọ́jú bẹ́ẹ̀ ṣàǹfààní fún, ṣùgbọ́n, ó tún ṣàǹfààní fún ọ̀pọ̀ míràn tí wọ́n ń ṣàníyàn nípa ewu fífa ẹ̀jẹ̀ síni lára.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo àwọn ìtẹ̀jáde Jí!, November 22, 1993, ojú ìwé 24 sí 27, àti January 22, 1996, ojú ìwé 31.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]

Fọ́tò WHO láti ọwọ́ P. Almasy

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́