ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 9/15 ojú ìwé 25
  • Ìtàn Àròsọ Ìkún Omi Ti Àkọsílẹ̀ Bíbélì Lẹ́yìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtàn Àròsọ Ìkún Omi Ti Àkọsílẹ̀ Bíbélì Lẹ́yìn
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 9/15 ojú ìwé 25

Ìtàn Àròsọ Ìkún Omi Ti Àkọsílẹ̀ Bíbélì Lẹ́yìn

KÚNYA kárí ayé ti ọjọ́ Nóà jẹ́ òtítọ́ ọ̀rọ̀ ìtàn. A rí onírúurú ìtàn náà nínú ìtàn àtẹnudẹ́nu ọ̀pọ̀ ilẹ̀ kárí ayé. Ní orílẹ̀-èdè Áfíríkà náà, Ṣáàdì, àwọn ẹ̀yà Moussaye ṣàlàyé Ìkún Omi náà lọ́nà yìí:

‘Ní ìgbà kan, ìdílé kan ń gbé ní ibì kan tí ó jìnnà réré. Ní ọjọ́ kan, ìyá ìdílé yìí fẹ́ gbọ́ oúnjẹ àjẹgbádùn fún ìdílé rẹ̀. Nítorí náà, ó gbé odó àti ọmọdó rẹ̀ láti gún ọkà di ìyẹ̀fun. Nígbà yẹn, òfuurufú sún mọ́ ilẹ̀ ju bí ó ṣe rí nísinsìnyí lọ. Ní tòótọ́, bí o bá na ọwọ́ rẹ sókè, o lè fi ọwọ́ kàn án. Ó fi gbogbo okun rẹ̀ gún ọkà náà, ọkà bàbà tí ó sì ń gún di ìyẹ̀fun ní wàrà-ǹ-wéré. Ṣùgbọ́n bí ó ti ń gún un, obìnrin náà fi àìkíyèsára gbé ọmọdó sókè jù, ó sì dá òfuurufú lu! Lọ́gán, alagbalúgbú omi bẹ̀rẹ̀ sí í ya sórí ilẹ̀ ayé. Kì í ṣe òjò lásán ni èyí. Ó rọ̀ fún ọ̀sán méje àti òru méje títí tí omi fi bo gbogbo ilẹ̀ ayé. Bí òjò náà ti ń rọ̀, òfuurufú bẹ̀rẹ̀ sí í ròkè títí tí ó fi dé ibi tí ó wà nísinsìnyí—ibi gíga, tí ọwọ́ kò lè tó. Ẹ wo àjálù ńlá tí ó jẹ́ fún ẹ̀dá ènìyàn! Láti ìgbà yẹn wá, a ti pàdánù àǹfààní fífi ọwọ́ wa kan òfuurufú.’

Lọ́nà tí ó dùn mọ́ni, káàkiri ayé, a lè rí àwọn ìròyìn ìgbàanì tí ń sọ nípa ìkún omi kan tí ó kárí ilẹ̀ ayé. Àwọn ọmọ ìbílẹ̀ ilẹ̀ America, títí kan àwọn Aborigine ti Australia, ní ìtàn nípa rẹ̀. Kúlẹ̀kúlẹ̀ lè yàtọ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ jù lọ ìròyìn ní èrò pé omi bo ilẹ̀ ayé nínú, àti pé àwọn ènìyàn díẹ̀ ni ó là á já nínú ọkọ̀ òbèlè àtọwọ́dá kan. Ìtànkálẹ̀ ẹṣin ọ̀rọ̀ yìí ti òkodoro òtítọ́ náà lẹ́yìn pé Àkúnya kárí ayé ṣẹlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a ti ròyìn nínú Bíbélì.—Jẹ́nẹ́sísì 7:11-20.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́