Ìmúṣẹ Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì
AGOGO àrà ọ̀tọ̀ kan àti òǹkà onínọ́ńbà abánáṣiṣẹ́ kan wà níbi tí a pàtẹ wọn sí ní Ilé Àkójọ Ohun Ìṣẹ̀ǹbáyé Ogun ti Olú Ọba ní London, England. Bí aago náà ti ń yí, òǹkà náà ń ṣẹ́jú wáíwáí ní gbogbo 3.31 ìṣẹ́jú àáyá. Bí ó bá ti ṣẹ́jú wáí lẹ́ẹ̀kan, nọ́ńbà míràn yóò kún àròpọ̀ náà. Ṣíṣẹ́jú wáí kọ̀ọ̀kan, nọ́ńbà kọ̀ọ̀kan, dúró fún ọkùnrin kan, obìnrin kan, tàbí ọmọdé kan tí ogun ti pa ní ọ̀rúndún yìí.
Òǹkà náà bẹ̀rẹ̀ kíkà rẹ̀ ní June 1989, a sì retí pé kí ó parí kíkà náà ní ọ̀gànjọ́ òru tí yóò bẹ̀rẹ̀ ọdún 2000. Nígbà náà, iye tí yóò wà lórí òǹkà náà yóò jẹ́ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà ọgọ́rùn-ún—iye ikú tí a fojú díwọ̀n pé ó jẹ mọ́ ogun jálẹ̀ ọ̀rúndún ogún.
Ní nǹkan bí 2,000 ọdún sẹ́yìn, Jésù Kristi sọ tẹ́lẹ̀ nípa àkókò kan tí ‘orílẹ̀-èdè tí ń dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba tí ń dìde sí ìjọba’ yóò sàmì sí. Ní ìbámu pẹ̀lú ìyẹn, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń wàásù tipẹ́tipẹ́ pé àwọn ogun runlérùnnà ti ọ̀rúndún yìí, pa pọ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìsẹ̀lẹ̀, àjàkálẹ̀ àrùn, àìtó oúnjẹ, àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ míràn, lápapọ̀ pèsè ẹ̀rí pé a ń gbé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn”—sáà náà tí ó tẹ̀ lé gbígbé Kristi gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba ní ọ̀run ní ọdún 1914.—Lúùkù 21:10, 11; Tímótì Kejì 3:1.
Ní lílo Bíbélì gẹ́gẹ́ bí ọlá àṣẹ rẹ̀, Ilé Ìṣọ́ ń kéde ìhìn rere pé, láìpẹ́, Ìjọba Ọlọ́run yóò pa àwọn aninilára run, yóò sì sọ ilẹ̀ ayé di párádísè kan. Kí ni yóò sì ṣẹlẹ̀ sí ọjọ́ ọ̀la ogun? Bíbélì wí pé: “Ẹ wá wo àwọn ìgbòkègbodò Jèhófà, bí ó ti gbé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ayanilẹ́nu kalẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Ó mú kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé. Ó ṣẹ́ ọrun sí wẹ́wẹ́, ó sì ké ọ̀kọ̀ sí wẹ́wẹ́; ó sun àwọn kẹ̀kẹ́ [ogun] nínú iná.”—Orin Dáfídì 46:8, 9, NW.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]
Agogo: Nípasẹ̀ Ìyọ̀ọ̀da Onínúure ti Imperial War Museum