Ìwé Ìròyìn Tí Ń gún Ọkàn Ní Kẹ́ṣẹ́
ÀÌLÓǸKÀ ìwé ìròyìn ni a ń tẹ̀ jáde yíká ayé láti tẹ́ àìní àwọn òǹkàwé tí ebi ìsọfúnni tàbí eré ìnàjú ń pa lọ́rùn.
Kí ni ó mú kí ìwé ìròyìn tí ń bẹ lọ́wọ́ rẹ yìí yàtọ̀? Lẹ́tà tí ó tẹ̀ lé e yìí, tí ọ́fíìsì ẹ̀ka Watch Tower Society ní Germany rí gbà, lè pèsè ìdáhùn:
“Ẹ̀yin arákùnrin ọ̀wọ́n, mó dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ yín fún ìsapá àti iṣẹ́ yín. Nígbà tí èmi àti àwọn ọmọkùnrin mi méjèèjì padà dé láti ìpàdé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé agogo 9:30 alẹ́ ti lù, mo ṣáà fẹ́ tẹ́tí sí Ilé Ìṣọ́ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé [lórí kásẹ́ẹ̀tì àtẹ́tísí]. Bí mo ṣe ń fọ àwo, mo bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ àkọ́kọ́ (April 1, 1995). Mo nímọ̀lára pé, ó yẹ kí n tẹ́tí sí i ju ẹ̀ẹ̀kan lọ, nítorí náà mo dá iṣẹ́ mi nínú ilé ìdáná dúró, mo sì ń fojú bá ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà [“Ẹ Ṣe Iyebíye Lójú Ọlọrun!”] nínú Ilé Ìṣọ́ lọ, bí mo ṣe ń tẹ́tí sí téèpù. Ó gún ọkàn mi ní kẹ́ṣẹ́, ní pàtàkì ìpínrọ̀ ìkẹrin àti ìkarùn-ún. Lẹ́yìn náà omi bẹ̀rẹ̀ sí í dà lójú mi—ṣùgbọ́n kì í ṣe fún ìgbà pípẹ́. Mó dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé mo wà láàyè àti pé mo wà lára àwọn ènìyàn rẹ̀ àti pé, èmi, àti ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn, lè sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ̀. Kò sí ìdí kankan láti nímọ̀lára àìjámọ́ nǹkan kan. Ẹ̀mí Jèhófà wà pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀. Ǹjẹ́ kí gbogbo wa lè máa fara dà á, kí a sì lè dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́, kí a wà ní ìṣọ̀kan. Pẹ̀lú ìfẹ́ni Kristẹni, arábìnrin yín nínú ìgbàgbọ́.”
Ilé Ìṣọ́ ń pèsè ohun tí ó ju ìsọfúnni lọ. Ó ń gún ọkàn àwọn tí ń kà á ní kẹ́ṣẹ́, ó sì n tẹ́ àìní wọn fún oúnjẹ tẹ̀mí àti ìṣírí àsìkò lọ́rùn. Bẹ́ẹ̀ ni, Ilé Ìṣọ́ ń pèsè “oúnjẹ . . . ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.”—Mátíù 24:45.