ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 10/15 ojú ìwé 32
  • ‘Jèhófà Dáhùn Àdúrà Mi!’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘Jèhófà Dáhùn Àdúrà Mi!’
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 10/15 ojú ìwé 32

‘Jèhófà Dáhùn Àdúrà Mi!’

JÁKÈJÁDÒ ayé, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń darí ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ to mílíọ̀nù márùn-ún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí wọ́n ní ọkàn-ìfẹ́ nínú jíjèrè ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run àti ète àgbàyanu rẹ̀ fún aráyé. Àní àwọn tí ó jẹ́ ọmọdé láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ yìí. Fún àpẹẹrẹ, ṣàgbéyẹ̀wò ọmọdékùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Joel. Ó fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ rẹ̀ hàn sí Jèhófà, a sì batisí rẹ̀ nígbà tí ó wà ní ọmọ ọdún mẹ́sàn-án. Ọdún kan lẹ́yìn náà, ó ní ìrírí yìí:

“Nígbà tí mo wà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́, mo pàdé obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Candy. Mo fi ìwé pẹlẹbẹ náà, ‘Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun,’ lọ̀ ọ́. Ó ti ní in tẹ́lẹ̀, nítorí náà mo fi ìwé náà, Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye, lọ̀ ọ́. Ó ti ni ìyẹn pẹ̀lú tẹ́lẹ̀. Lẹ́yìn náà mo ronú pé, ‘n óò fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ obìnrin yìí.’ Ó gbà bẹ́ẹ̀!

“Arábìnrin Candy, tí àrùn káńsà ń pa kú lọ, wá gbé ní ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ní àfikún sí i, Candy ń kẹ́kọ̀ọ́ láti di nọ́ọ̀sì. Nítorí náà, fún sáà kan, a dá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà dúró. Ṣùgbọ́n, èmi àti àwọn òbí mi máa ń kàn sí i nípa fífún òun tàbí ọkọ rẹ̀, Dick, ní ìwé ìròyìn. Ó sọ fún wa pé aya òún máa ń kó àwọn ìwé ìròyìn náà síbi ibùsùn rẹ̀, ó sì máa ń kà wọ́n ní alẹ́.

“Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, arábìnrin Candy kú. Èmi àti Bàbá mi àti Ìyá mi bá Candy sọ̀rọ̀ nípa ipò tí àwọn òkú wà. Ó pinnu láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i. Ní ọjọ́ mìíràn, a béèrè lọ́wọ́ Dick bí yóò bá fẹ́ kí a máa bá òun pẹ̀lú Candy kẹ́kọ̀ọ́ pa pọ̀ kí a sì sọ ọ́ di ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé. Ó ronú pé èrò yẹ́n dára. Nítorí náà nísinsìnyí, èmi pẹ̀lú Bàbá mi ń bá Dick àti Candy ṣèkẹ́kọ̀ọ́. Wọ́n ń tẹ̀ síwájú dáradára, wọ́n sì fi ìmọrírì hàn fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

“Mo ti máa ń gbàdúrà fún níní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan, Jèhófà sì dáhùn àdúrà mi!”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́