Ìtùnú Láàárín Ọdún Mẹ́rin Tí Ogun Fi Jà
LÁÀÁRÍN ọdún mẹ́rin tí ogún fi jà ní agbègbè ìpínlẹ̀ Yugoslavia tẹ́lẹ̀ rí, ọ̀pọ̀ ènìyàn jìyà púpọ̀, àwọn ohun èèlò sì wọ́n gógó. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ń fi ìṣòtítọ́ jọ́sìn “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo” wà lára wọn.—Kọ́ríńtì Kejì 1:3.
Ní Sarajevo, ìnira púpọ̀ ti gbígbé ní ìlú ńlá tí a sàga tì jálẹ̀ ogun náà dé bá àwọn ènìyàn. Iná mànàmáná ń lọ nígbà gbogbo, omi ẹ̀rọ kò yọ déédéé, igi ìdáná kò tó, oúnjẹ kò sì tó nǹkan. Báwo ni Ìjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Sarajevo ṣe ń bá a nìṣó lábẹ́ àwọn ipò lílégbá kan wọ̀nyí? Àwọn Kristẹni láti ilẹ̀ tí ó múlé gbè wọ́n fi ẹ̀mí ara wọn wewu láti kó ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìpèsè ìrànwọ́ wá. (Wo Ilé-Ìṣọ́nà, November 1, 1994, ojú ìwé 23 sí 27.) Bákan náà, àwọn ará ní Sarajevo ṣàjọpín ohun tí wọ́n ní pẹ̀lú ara wọn, ní gbígbé ìjẹ́pàtàkì jù lọ karí ṣíṣàjọpín nǹkan tẹ̀mí. Nígbà ìsàgatì náà, Kristẹni alábòójútó kan láti ìlú yẹn fúnni ní ìròyìn tí ó tẹ̀ lé e yìí:
“A ka ìpàdé wa sí gan-an. Èmi àti aya mi, pa pọ̀ pẹ̀lú 30 ènìyàn míràn, máa ń fẹsẹ̀ rin kìlómítà 15 [ibùsọ̀ 9], ní àlọ àti àbọ̀, láti lọ sí ìpàdé. Nígbà kan, ìjọba kéde pé omi yóò yọ ní àkókò tí a ń ṣe ìpàdé lọ́wọ́. Kí ni àwọn ará yóò ṣe? Ṣé kí wọ́n jókòó sílé ni, tàbí kí wọ́n lọ sí ìpàdé? Àwọn ará wa yàn láti lọ sí ìpàdé. Àwọn ará sábà máa ń ran ara wọn lọ́wọ́ lẹ́nì kíní kejì; ohun yòó wù tí wọ́n bá ní, wọn yóò ṣàjọpín rẹ̀. Arábìnrin kan nínú ìjọ wa ń gbé ní ẹ̀yìn odi ìlú, nítòsí igbó; nítorí náà ó rọrùn díẹ̀ fún un láti rí igi ìdáná díẹ̀. Ó tún ń ṣiṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ búrẹ́dì, wọ́n sì ń fi ìyẹ̀fun san owó oṣù fún un. Nígbà tí ó bá ṣeé ṣe, yóò ṣe búrẹ́dì ńlá, yóò sì gbé e wá sí ìpàdé. Lẹ́yìn ìpàdé, lẹ́nu ọ̀nà àbájáde, yóò máa fún ẹnì kọ̀ọ̀kan ní ègé kọ̀ọ̀kan.
“Ó ṣe pàtàkì pé kí arákùnrin tàbí arábìnrin wa kankan máà nímọ̀lára pé a pa òun tì. Kò sí ẹni tó mọ ẹni tí yóò nílò ìrànlọ́wọ́ nínú ipò kan tí kò bára dé nínú wa. Nígbà tí yìnyín kún ojú ọ̀nà, tí ara arábìnrin kan kò sì dá, àwọn arákùnrin tí wọ́n jẹ́ abarapá fi ọmọlanke orí yìnyín tì í wá sí ìpàdé.
“Gbogbo wa ní ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù, Jèhófà sì ti bù kún ìsapá wa. Ó ti rí ipò tí ń páni láyà tí a wà ní Bosnia, ṣùgbọ́n ó ti fi ìbísí bù kún wa—ìbísí tí a kò rí kí ogun tó bẹ̀rẹ̀.”
Bákan náà, ní àwọn apá ibòmíràn tí ogun ti fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ ní Yugoslavia tẹ́lẹ̀ rí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti gbádùn ìbísí láìka ìnira líle koko sí. Láti ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Croatia ni ìròyìn yìí ti wá nípa àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí kan: “Nǹkan kò rọgbọ rárá fún àwọn ará tí ń gbé ní Velika Kladuša. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni a kọ lu ìlú náà. Àwọn ará náà ní láti ṣàlàyé ipò àìdásí tọ̀tún tòsì wọn fún ọmọ ogun àwọn Croatia, Serbia, àti onírúurú ọmọ ogun Mùsùlùmí. Ó dájú pé, wọ́n ní láti fara da ohun púpọ̀—ìfisẹ́wọ̀n, ìluni, ebi, ewu ikú. Síbẹ̀, gbogbo wọn dúró gẹ́gẹ́ bí olùṣòtítọ́, wọ́n sì ní àǹfààní títa yọ lọ́lá ti rírí ìbùkún Jèhófà lórí àwọn ìgbòkègbodò wọn.”
Láìka àwọn ìnira wọ̀nyí sí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Velika Kladuša àti Bihać tí ó múlé gbè é ń bá a nìṣó láti gbádùn ìbísí, bí wọ́n ṣe ń fi tìtaratìtara ṣàjọpín ìhìn iṣẹ́ ìtùnú Ọlọ́run pẹ̀lú àwọn aládùúgbò wọn. Àpapọ̀ akéde Ìjọba 26 láti àwọn ibi méjèèjì wọ̀nyí ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì 39 nínú ilé!