“Ìdílé kan náà ni Gbogbo Wa”
NÍ ÀWỌN ọdún àìpẹ́ yìí, ẹ̀tanú ìsìn àti ẹ̀yà ìran tèmi lọ̀gá ti tàn kálẹ̀ kárí ilẹ̀ ayé. Ìyàtọ̀ ẹ̀yà ìran ti tanná ran ìpànìyàn, ìdánilóró, àti àwọn ìwà ìkà bíburú jáì tí ń tini lójú mìíràn. Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn kan láti ọwọ́ Àjọ Abẹ̀bẹ̀fúndàáríjì Lágbàáyé ṣe sọ, títẹ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lójú ti fipá mú kí èyí tí ó ju mílíọ̀nù 23 ènìyàn jákèjádò ayé sá fi ilé wọn sílẹ̀ ní ọdún 1994.
Ní Rwanda nìkan, a pa nǹkan bíi 500,000 ènìyàn, èyí tí ó sì ju 2,000,000 mìíràn di olùwá-ibi-ìsádi lẹ́yìn tí ìwà ipá bẹ́ sílẹ̀ láàárín àwọn Tutsi àti àwọn Hutu. Ìwé agbéròyìnjáde náà, Le Soir, ti Belgian, ròyìn pé: “A ṣenúnibíni sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní pàtàkì nítorí kíkọ̀ tí wọ́n kọ̀ láti gbé ohun ìjà.” Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í lọ́wọ́ nínú ìforígbárí oníhàámọ́ra. Síbẹ̀síbẹ̀, ọgọ́rọ̀ọ̀rún wọn ni a pa nínú ìwà ipá náà. Èyí rán wa létí àwọn ọ̀rọ̀ Jésù sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Nítorí pé ẹ kì í ṣe apá kan ayé, . . . ni ayé fi kórìíra yín.”—Jòhánù 15:19.
Ìdílé Ẹlẹ́rìí kan—Eugène Ntabana, aya rẹ̀, àti àwọn ọmọ méjì—ń gbé ní Kigali, tí í ṣe olú ìlú. Nígbà tí ó bá ń ṣàlàyé àìdásítọ̀túntòsì Kristẹni fún àwọn aládùúgbò rẹ̀, Eugène sábà máa ń sọ nípa àjàrà bougainvillea, àjàrà kan tí ó máa ń fà mọ́ nǹkan, tí ó máa ń ṣe dáradára ní ipò àyíká tí ó móoru.—Mátíù 22:21.
Eugène máa ń ṣàlàyé pé: “Níhìn-ín ní Kigali, àjàrà bougainvillea máa ń mú òdòdó pupa, pupa rẹ́súrẹ́sú, àti funfun jáde nígbà míràn. Síbẹ̀, gbogbo wọ́n jẹ́ ọ̀kan náà. Bákan náà ni ó rí pẹ̀lú ẹ̀dá ènìyàn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè jẹ́ ẹ̀yà ìran ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, àwọ̀ ara ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, tàbí ipò àtilẹ̀wá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní ti ẹ̀yà ìran, ara ìdílé kan náà ni gbogbo wa, ìdílé aráyé.”
Lọ́nà tí ó bani nínú jẹ́, láìka jíjẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́tù wọn ní ti ẹ̀dá, àti àìdásítọ̀túntòsì wọn sí, àgbájọ àwọn ènìyànkénìyàn tí òùngbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ ṣìkà pa ìdílé Ntabana. Láìka ìyẹn sí, wọ́n kú ní olùṣòtítọ́. A lè ní ìdánilójú pé Jèhófà Ọlọ́run yóò mu ìlérí rẹ̀ fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ṣẹ, a óò sì jí wọn dìde láti jogún ayé kan níbi tí ẹ̀tanú kì yóò sí mọ́. (Ìṣe 24:15) Nígbà náà, ìdílé Ntabana, pẹ̀lú àwọn mìíràn, yóò “máa ṣe inú dídùn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.”—Orin Dáfídì 37:11.