ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 2/1 ojú ìwé 29
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Fifi Ẹ̀jẹ̀ Gba Ẹmi Là—Bawo?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Fi Ojú Pàtàkì Wo Ẹ̀bùn Ìwàláàyè Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 2/1 ojú ìwé 29

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn ti sọ, lẹ́yìn tí a bá bí ọmọ kan tán, àwọn ilé ìwòsàn kan ń tọ́jú ibi ọmọ àti ìwọ́ láti fa àwọn ohun kan yọ láti inú ẹ̀jẹ̀ tí ń bẹ nínú wọn. Kristẹni kan ha ní láti dààmú nítorí èyí bí?

Ní ọ̀pọ̀ ilé ìwòsàn, nǹkan bí ìyẹn kì í wáyé, nítorí náà, àwọn Kristẹni kò ní láti dààmú. Bí ìdí pàtàkì bá wà láti gbà gbọ́ pé a ń tẹ̀ lé irú àṣà bẹ́ẹ̀ ní ilé ìwòsàn tí Kristẹni kan yóò bímọ sí, yóò bá a mu wẹ́kú láti fi tó dókítà létí pé kí ó kó ibi ọmọ àti ìwọ́ náà dà nù, kí ó má ṣe lò ó ní ọ̀nà yòó wù kí ó jẹ́.

Onírúurú àwọn èlò ìṣègùn ní a ti mú láti inú àwọn ohun ẹlẹ́mìí, yálà ẹranko tàbí ènìyàn. Fún àpẹẹrẹ, àwọn omi ìsúnniṣe inú ara kan ni a mú jáde láti inú ìtọ̀ ẹṣin tí ó lóyún. Ẹ̀jẹ̀ ẹṣin ti jẹ́ orísun kan fún abẹ́rẹ́ àjẹsára fún àrùn ipá, tipẹ́tipẹ́ sì ni a ti ń mú èròjà gamma globulin, tí ń gbéjà ko àrùn jáde láti inú ẹ̀jẹ̀ tí ń bẹ nínú ibi ọmọ (èkejì ọmọ) ẹ̀dá ènìyàn. Àwọn ilé ìwòsàn kan ti tọ́jú ibi ọmọ, wọ́n sì ti mú kí ó dì, tí ibi ìwádìí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ tí a ti ń poògùn sì wá kó wọn lọ lẹ́yìn náà láti lè ṣaáyan ẹ̀jẹ̀ náà, tí ó kún fún àwọn ohun agbóguntàrùn láti mú èròjà gamma globulin jáde láti inú rẹ̀.

Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn olùṣèwádìí ti kẹ́sẹ járí ní lílo ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n rí láti inú èkejì ọmọ láti ṣe ìtọ́jú irú àrùn leukemia kan, a sì ti sọ pé irú ẹ̀jẹ̀ bẹ́ẹ̀ lè wúlò fún títọ́jú àwọn ìṣiṣẹ́gbòdì ètò ìgbékalẹ̀ ààbò inú ara mélòó kan tàbí láti fi dípò pípààrọ̀ mùndùnmúndùn eegun. Fún ìdí èyí, ìròyìn díẹ̀ ti tàn kálẹ̀ nípa àwọn òbí tí wọ́n ń gba ẹ̀jẹ̀ láti inú èkejì ọmọ, tí wọ́n ń mú kí ó dì, tí wọ́n sì ń fi pa mọ́ nítorí bí yóò bá wúlò fún ìtọ́jú ọmọ wọn lẹ́yìn ọ̀la.

Irú lílo ẹ̀jẹ̀ inú ibi ọmọ fún èrè bẹ́ẹ̀ kò lè fa àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ́ra, àwọn tí wọ́n ń jẹ́ kí òfin pípé ti Ọlọ́run máa tọ́ èrò wọn. Ẹlẹ́dàá wa ń wo ẹ̀jẹ̀ bí ohun mímọ́ ọlọ́wọ̀, tí ó dúró fún ìwàláàyè tí Ọlọ́run fúnni. Ọ̀nà kan ṣoṣo tí òun fàṣẹ sí láti lo ẹ̀jẹ̀ jẹ́ lórí pẹpẹ, ní ìsopọ̀ pẹ̀lú àwọn ìrúbọ. (Léfítíkù 17:10-12; fi wé Róòmù 3:25; 5:8; Éfésù 1:7.) Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, a gbọ́dọ̀ da ẹ̀jẹ̀ tí a bá mú jáde láti ara ìṣẹ̀dá sórí ilẹ̀ ni, kí a dà á nù.—Léfítíkù 17:13; Diutarónómì 12:15, 16.

Nígbà tí àwọn Kristẹni ba ṣọdẹ ẹran tàbí tí wọ́n bá pa adìyẹ tàbí ẹlẹ́dẹ̀, wọ́n máa ń ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, wọ́n sì ń dà á nù. Kò pọn dandan pé kí wọ́n dà á sórí ilẹ̀ ní ti gidi, nítorí kókó tí ó wà níbẹ̀ ni pé wọ́n gbọ́dọ̀ da ẹ̀jẹ̀ náà nù dípò lílò ó lọ́nàkọ́nà.

Àwọn Kristẹni tí a bá gbé lọ sí ilé ìwòsàn lóye pé a gbọ́dọ̀ da àwọn èròjà ara tí a bá mú kúrò lára wọn nù, yálà èròjà náà jẹ́ ìdọ̀tí ara, ìṣù ẹran tí ó ti ni àrùn, tàbí ẹ̀jẹ̀. Òtítọ́ ni pé, dókítà kan lè fẹ́ láti kọ́kọ́ ṣe àwọn àyẹ̀wò kan, irú bíi fífi kẹ́míkà ṣàyẹ̀wò ìtọ̀, ṣíṣàyẹ̀wò kòkòrò àrùn inú ìṣù ẹran oníkókó ọyún, tàbí àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn náà, a óò da àwọn èròjà náà nù ní ìbámu pẹ̀lú òfin àdúgbò. Àwọn aláìsàn ní ilé ìwòsàn kò fi bẹ́ẹ̀ nílò láti béèrè lọ́nà àkànṣe fún èyí nítorí pé ó bá ọgbọ́n mu, ó sì bá ọgbọ́n ìṣègùn mu láti da àwọn èròjà ara bẹ́ẹ̀ nù. Bí aláìsàn kan bá ní ìdí tí ó dájú láti ṣiyè méjì pé a óò tẹ̀ lé irú àṣà tí ó bójú mu bẹ́ẹ̀, ó lè mẹ́nu kàn án fún dókítà tí ọ̀ràn kàn, ní sísọ pé fún ìdí tí ó jẹ́ ti ìsìn, òun ń fẹ́ kí a da gbogbo irú èròjà bẹ́ẹ̀ sọnù.

Bí ó ti wù kí ó rí, gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ, èyí kì í fi bẹ́ẹ̀ jẹ́ ìdààmú fún aláìsàn ní gbogbogbòò nítorí pé ní àwọn ibi púpọ̀, irú fífi èkejì ọmọ, tàbí àwọn èròjà ara mìíràn pa mọ́ bẹ́ẹ̀ àti títún wọn lò ni a kì í tilẹ̀ ronú nípa rẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í ṣe àṣà tí a ń tẹ̀ lé.

Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, “Ẹ Jẹ́ Kí A Kórìíra Ohun Búburú Tẹ̀gàntẹ̀gàn,” tí ó fara hàn nínú Ilé Ìṣọ́ ti January 1, 1997, dà bí ẹni darí àfiyèsí sí

yíyan ọmọdé láàyò fún ìbálòpọ̀. Kí ni a túmọ̀ àṣà yí sí?

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, Webster’s Ninth New Collegiate Dictionary, túmọ̀ “yíyan ọmọdé láàyò fún ìbálòpọ̀” gẹ́gẹ́ bí “ìgbégbòdì ìbálòpọ̀ nínú èyí tí ó jẹ́ pé àwọn ọmọdé ni a yàn láàyò.” A dẹ́bi fún àwọn apá àṣà yí kan nínú Diutarónómì 23:​17, 18. Níbẹ̀ Ọlọ́run sọ̀rọ̀ lòdì sí dídi aṣẹ́wó nínú tẹ́ńpìlì (“tàbí, ‘ọmọdékùnrin tí abọ́mọdé-ṣèṣekúṣe ń bá lò pọ̀,’ ọmọdékùnrin kan tí a ń lò fún ète ìgbégbòdì ìbálòpọ̀,” àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé). Àwọn ẹsẹ wọ̀nyí tún ka ẹnikẹ́ni léèwọ̀ láti mú iye owó “ajá” wá sí “ilé OLÚWA” (“ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ abọ́mọdé-ṣèṣekúṣe kan; ẹnì kan tí ń lọ́wọ́ nínú ìbálòpọ̀ àgbafùrọ̀ṣe, ní pàtàkì pẹ̀lú ọmọdékùnrin,” àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé). Àwọn ìtọ́kasí Ìwé Mímọ́ àti ti ìwé ayé wọ̀nyí f ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, ohun tí Ilé Ìṣọ́ náà ń jíròrò ni kí àgbàlagbà kan sọ ọmọ kan di ẹni tí ó ń bá ṣèṣekúṣe, títí kan fífọwọ́ pa á lára.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́