Ìjagunmólú Mìíràn fún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Ilẹ̀ Gíríìsì
NÍ October 6, 1995, Ilé Ẹjọ́ Májísíréètì, tí ó jẹ́ onímẹ́ńbà mẹ́ta ní Áténì gbọ́ ẹjọ́ kan tí ó kan àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún méjì ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ẹ̀sùn sísọni di aláwọ̀ṣe ni a fi kàn wọ́n, ọ̀gá ọlọ́pàá kan ni ó sì pè wọ́n lẹ́jọ́ lẹ́yìn tí Àwọn Ẹlẹ́rìí ṣe ìbẹ̀wò sí ilé rẹ̀.
Ìbéèrè tí adájọ́ tí ó jẹ́ alága béèrè fi hàn pé ó ní ọkàn ìfẹ́ gidigidi nínú iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Fún àpẹẹrẹ, ó béèrè pé: “Ó ti tó ìgbà wo tí ẹ ti ń ṣe iṣẹ́ yìí? Báwo ni àwọn ènìyàn ti ń hùwà sí i yín láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá? Irú ìdáhùnpadà wo ni ó ti wà sí iṣẹ́ yín? Kí ni ẹ máa ń sọ fún àwọn ènìyàn lẹ́nu ọ̀nà wọn?” Gbogbo àwọn tí ó wà ní yàrá ilé ẹjọ́ tẹ́tí sílẹ̀ bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí ẹ̀rí mímúnádóko tí a jẹ́.
Sí ìyàlẹ́nu Àwọn Ẹlẹ́rìí náà, agbẹjọ́rò olùpẹ̀jọ́ pàápàá sọ̀rọ̀ gbè wọ́n. Ó sọ nínú àsọparí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Kìí ṣe kìkì pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ẹ̀tọ́ lábẹ́ òfin láti gbà gbọ́ nínú Ọlọ́run wọn, kí wọ́n sì jọ́sìn rẹ̀ nìkan ni, ṣùgbọ́n wọ́n tún lè tan ìgbàgbọ́ wọn kálẹ̀ ní ẹnu ọ̀nà dé ẹnu ọ̀nà, ní ìta gbangba, àti ní òpópónà, àní ní pípín àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn lọ́fẹ̀ẹ́ bí wọ́n bá fẹ́ bẹ́ẹ̀.” Agbẹjọ́rò olùpẹ̀jọ́ tọ́ka sí onírúurú àwọn ìdájọ́ ẹ-ò-jẹ̀bi tí àwọn ilé ẹjọ́ àti Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Orílẹ̀-Èdè náà ṣe. Ó tún tọ́ka sí ẹjọ́ Kokkinakis òun ilẹ̀ Gíríìsì, nínú èyí tí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Ti Ilẹ̀ Europe ti dá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láre.a Agbẹjọ́rò olùpẹ̀jọ́ náà kìlọ̀ pé: “Ẹ jọ̀wọ́ rántí pé ilẹ̀ Gíríìsì tilẹ̀ san owó ìtánràn nínú ẹjọ́ yìí. Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra gidigidi nígbà tí a bá ké sí wa láti dá irú àwọn ẹjọ́ bẹ́ẹ̀. Ní tòótọ́, kò tilẹ̀ yẹ kí a gbé irú àwọn ẹjọ́ wọ̀nyí wá sí ilé ẹjọ́ rárá.”
Lẹ́yìn ọ̀rọ̀ agbẹjọ́rò olùpẹ̀jọ́, kò sí ohun púpọ̀ fún agbẹjọ́rò Àwọn Ẹlẹ́rìí láti sọ mọ́. Síbẹ̀síbẹ̀, ó lo àǹfààní náà láti tẹnu mọ́ ọn pé òfin ìsọnidaláwọ̀ṣe kò bá àgbékalẹ̀ òfin mu àti pé, ó ti ń kó ilẹ̀ Gíríìsì sínú ìṣòro lágbàáyé.
Adájọ́ tí ó jẹ́ alága wulẹ̀ wo àwọn adájọ́ méjì yòó kù lójú ni, wọ́n sì fohùn ṣọ̀kan ní dídá arákùnrin àti arábìnrin náà sílẹ̀ pé wọn kò jẹ̀bi. Ìgbẹ́jọ́ náà, tí ó gba wákàtí kan àti ìṣẹ́jú mẹ́wàá, jẹ́ ìjagunmólú fún orúkọ Jèhófà àti fún àwọn ènìyàn rẹ̀.
Ẹ̀ẹ̀kẹ́rin nìyí tí a óò dá wa sílẹ̀ pé a kò jẹ̀bi nínú ẹjọ́ ìsọnidaláwọ̀ṣe, lẹ́yìn tí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Ti Ilẹ̀ Europe gbọ́ ẹjọ́ Kokkinakis. Inú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ilẹ̀ Gíríìsì dùn pé àwọn ìṣòro tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìwàásù wọn dà bíi pé kò sí mọ́ nísinsìnyí àti pé, ó ṣeé ṣe láti máa bá iṣẹ́ náà nìṣó láìsí ìdíwọ́.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]