ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 4/1 ojú ìwé 30-31
  • Ìgbéyàwó Ọdún 403-wà Nínú Ìjọ̀ngbọ̀n

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìgbéyàwó Ọdún 403-wà Nínú Ìjọ̀ngbọ̀n
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 4/1 ojú ìwé 30-31

Ìgbéyàwó Ọdún 403-wà Nínú Ìjọ̀ngbọ̀n

NÍ Sweden, Ṣọ́ọ̀ṣì àti Orílẹ̀-Èdè ti gbádùn ipò ìbátan tímọ́tímọ́ fún ohun tí ó lé ní 400 ọdún. Nísinsìnyí, ìdè ìgbéyàwó tí ó so ìsìn àti ìjọba pọ̀ ti dẹ̀.

A fìdí ẹ̀sìn Luther múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀sìn Orílẹ̀-Èdè ní 1593, gbogbo àwọn ará Sweden sì ní láti jẹ́ mẹ́ńbà rẹ̀ tí a batisí. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, ní àwọn ọdún 1850, a ṣàtúnṣe kan. Kò pọn dandan mọ́ fún àwọn ará Sweden láti ṣe batisí; síbẹ̀síbẹ̀, a ṣì kà wọ́n sí mẹ́ńbà Ṣọ́ọ̀ṣì Luther. Nítorí náà, a béèrè pé kí wọ́n san ìpín 1 nínú ọgọ́rùn-ún owó orí owó tí ń wọlé fún wọn láti fi ti ṣọ́ọ̀ṣì lẹ́yìn àti láti fi san owó àwọn nǹkan tí ó ní í ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ ẹ̀tọ́ ìlú tí ṣọ́ọ̀ṣì ń ṣe. Láìpẹ́ yìí, ìyípadà míràn tún ṣẹlẹ̀. Láti 1952, àwọn ará Sweden lè kúrò nínú ṣọ́ọ̀ṣì lọ́nà tí ó bófin mu, kí a sì yọ̀ǹda wọn kúrò nínú sísan apá tí ó jọjú nínú owó orí ṣọ́ọ̀ṣì.

Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ẹ̀mú Ṣọ́ọ̀ṣì Luther kò fi bẹ́ẹ̀ múni mọ́ ní Sweden. Èyí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀, níwọ̀n bí ìpín 10 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn olùgbé Sweden ti jẹ́ àwọn aṣíwọ̀lú, tí wọn kì í ṣe ẹlẹ́sìn Luther, tí ó ní àwọn Júù, àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì, àti àwọn ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí nínú. Nípa báyìí, ní ìbẹ̀rẹ̀ 1996, kìkì ìpín 86 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ará Sweden ni wọ́n jẹ́ mẹ́ńbà Ṣọ́ọ̀ṣì Luther, iye náà sì ń dín kù sí i.

Ẹ̀mí ìdágunlá tí ń gbilẹ̀ sí i ń gbẹ́ ọ̀gbun kan sáàárín Ṣọ́ọ̀ṣì àti Orílẹ̀-Èdè. Ní báyìí, a ti polongo pé, kò pọn dandan kí ọba jẹ́ ẹlẹ́sìn Luther, a kò sì ka àwọn ọmọ èyíkéyìí tí òbí kan tí ó jẹ́ ẹlẹ́sìn Luther bá bí, sí mẹ́ńbà Ṣọ́ọ̀ṣì Luther ti Orílẹ̀-Èdè lójú ẹsẹ̀. Ní àfikún sí i, gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde, The Dallas Morning News ṣe sọ, nígbà tí yóò bá fi di ọdún 2000, “àwọn ṣọ́ọ̀ṣì àdúgbò àti orílẹ̀-èdè gbọ́dọ̀ ṣèdíwọ̀n, kí wọ́n sì pín ohun ìní wọn olówó gọbọi. Ṣọ́ọ̀ṣì gbọ́dọ̀ dín lára ìwéwèé ìnáwó rẹ̀ ọdọọdún ti 1.68 bílíọ̀nù dọ́là kù, ọ̀pọ̀ jù lọ èyí tí ń wá láti inú owó orí.” Lẹ́yìn tí ọ̀rúndún yìí bá parí, ṣọ́ọ̀ṣì yóò máa fúnra rẹ̀ yan bíṣọ́ọ̀bù.

Bí ẹ̀mí ìdágunlá àti ìjórẹ̀yìn ṣe ń dé bá Kirisẹ́ńdọ̀mù, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Sweden ń bá a nìṣó láti gbilẹ̀ sí i. Ìwé 1997 Yearbook of Jehovah’s Witnesses ròyìn pé 24,487 akéde Ìjọba Ọlọ́run ni ó wà ní ilẹ̀ yẹn, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìpín 10 nínú ọgọ́rùn-ún nínú wọn tí ń wàásù gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà alákòókò kíkún. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn wọ̀nyí ń nàgà fún àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn púpọ̀ sí i. Fún àpẹẹrẹ, ní àkókò àpéjọpọ̀ àgbègbè Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní 1995, 20 tọkọtaya fi fọ́ọ̀mù ìkọ̀wé béèrè fún dídi míṣọ́nnárì tí a dá lẹ́kọ̀ọ́ ní Watchtower Bible School of Gilead sílẹ̀. Títí di ìgbà yẹn, nǹkan bí 75 akẹ́kọ̀ọ́yege tí wọ́n jẹ́ ará Sweden ti kíláàsì tí ó ti kọjá ni ó wà, tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì ní àwọn apá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lágbàáyé. Kò sí iyè méjì pé, àpẹẹrẹ rere àti àwọn lẹ́tà afúnni níṣìírí wọn àti ìbẹ̀wò wọn ní ipa ríruni sókè lórí àwọn tí ń ronú nípa àǹfààní kíkọyọyọ yìí nísinsìnyí.

Nípa báyìí, bí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ní Kirisẹ́ńdọ̀mù ṣe ń jìyà ẹ̀mí tí kò gbéṣẹ́ mọ́, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà “kọrin fún inú dídùn.”—Aísáyà 65:13, 14.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 30]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Sweden

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́