A Óò Ha Fòpin Sí Irú Ìran Bí Èyí bí?
IBIKÍBI tí a bá yíjú sí lónìí, a ń rí ohun tí ń ṣàfihàn pákáǹleke, ìforígbárí, àti ogun. Ṣùgbọ́n, kì í ṣe ète ìwé ìròyìn yí láti fi kún gbogbo ìròyìn burúkú tí o ti gbọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, àkànṣe ìtẹ̀jáde yìí yóò mú ọ mọ ó kéré tán, àwọn òtítọ́ méjì tí ń tuni nínú. Àkọ́kọ́, pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ìgbàanì nínú Bíbélì ní ti gidi sọ tẹ́lẹ̀ nípa ọ̀pọ̀ jù lọ nínú àwọn ìròyìn burúkú tí ń múni gbọ̀n rìrì ní sànmánì wa; ìkejì, pé ìwé àsọtẹ́lẹ̀ kan náà yí, sọ tẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ kan, nígbà tí irú ìran tí a rí níhìn-ín yóò di ohun àtijọ́. Kò ní sí ogun mọ́. Kò ní sí jíju bọ́ǹbù, yíyìnbọnluni, ríri ohun abúgbàù mọ́lẹ̀, tàbí ìkópayàbáni mọ́. Kò ní sí àwọn ọmọ òrukàn tí làásìgbò bá tàbí àwọn olùwá-ibi-ìsádi tí wọn kò rílé gbé. Ayé alálàáfíà tòótọ́, tí ń tu ọkàn lára. Ìwọ yóò ha fẹ́ láti rí irú àkókò bẹ́ẹ̀ bí? A rọ̀ ọ́ láti gbé ohun tí Bíbélì ní láti sọ yẹ̀ wò. O lè rí ìtùnú púpọ̀ níbẹ̀ ju bí o ṣe rò pé ó wà lọ.