A Mú Ìpèsè Oúnjẹ Tí Ó Tó fún Ayé Dáni Lójú Nípasẹ̀ Kí Ni?
LESTER BROWN, ààrẹ Ibùdó Worldwatch ní Washington, D. C., sọ pé: “Gbogbo ipa tí a lè sà pátápátá lè máà tó láti pèsè oúnjẹ tí ó tó lọ́nà tí a ti mọ̀ jù lọ ní ọ̀rúndún yìí.” Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn náà, New Scientist, ti sọ, ní ìbẹ̀rẹ̀ 1995, iye ọkà tí a kó pa mọ́ lágbàáyé wálẹ̀ sórí iye tí ó tí ì kéré jù lọ rí, tọ́ọ̀nù 255 mílíọ̀nù—iye tí ó tó bọ́ gbogbo ayé fún ọjọ́ 48 péré. Ní àwọn ọdún tí ó ṣáájú, nígbà tí iye tí a kó pa mọ́ kò lè bọ́ gbogbo ayé fún 60 ọjọ́, ó ṣeé ṣe láti mú ìpèsè náà wá sí àyè tí ó yẹ. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí, bí ó ti ṣeé ṣe tó fún ilẹ̀ ayé láti jèrè òfò rẹ̀ pa dà kò dá ibùdó Worldwatch lójú.
Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta ìkórè tí kò tó nǹkan, tí àwọn orílẹ̀-èdè tí ń gòkè àgbà, tí wọ́n ń pọ̀ sí i sì ń lo ọkà fún oúnjẹ ohun ọ̀sìn, ọkà tí ó jẹ́ ọba oúnjẹ fún àwọn tálákà kò tó nǹkan mọ́. Ìwé ìròyìn náà, New Scientist, kìlọ̀ pé, bí a kò bá tètè mójú tó ipò náà, ebi lè bẹ̀rẹ̀ sí í gbẹ̀mí àwọn bílíọ̀nù kan ènìyàn tí ń ná ìpín 70 nínú ọgọ́rùn-ún owó tí ń wọlé fún wọn lórí oúnjẹ.
Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé, àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé ní àkókò wa yóò nírìírí “àìtó oúnjẹ.” (Lúùkù 21:11) Síbẹ̀, Ọlọ́run kò dágunlá sí ìṣòro wa. Ní tòótọ́, àníyàn rẹ̀ fún ìṣòro aráyé ni a óò fi hàn nígbẹ̀yìngbẹ́yín nígbà tí Ìjọba rẹ̀ bá gba àkóso àlámọ̀rí ilẹ̀ ayé. Ní àkókò yẹn “ilẹ̀ yóò tó máa mú àsunkún rẹ̀ wá.” “Ìkúnwọ́ ọkà ni yóò máa wà lórí ilẹ̀, lórí àwọn òkè ńlá ni èso rẹ̀ yóò máa mì.” (Orin Dáfídì 67:6; 72:16) Nígbà náà, àwọn ọ̀rọ̀ alásọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí nípa Ẹlẹ́dàá yóò ní ìmúṣẹ pé: “Ìwọ bẹ ayé wò, o sì bomi rin ín . . . àfonífojì ni a fi ọkà bò mọ́lẹ̀.”—Orin Dáfídì 65:9, 13.
Ìlérí àgbàyanu yẹn ha fà ọ́ lọ́kàn mọ́ra bí? Ìwọ yóò ha fẹ́ láti mọ bí o ṣe lè jẹ́ apá kan rẹ̀ bí? Nígbà náà, ní kí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ púpọ̀ sí i fún ọ nípa ìlérí Párádísè nígbà míràn tí wọ́n bá kàn sí ẹnu ọ̀nà rẹ. Bí ìwọ yóò bá fẹ́ kí ẹnì kan wá sí ilé rẹ láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú rẹ lọ́fẹ̀ẹ́, jọ̀wọ́ kọ̀wé sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, Nigeria, tàbí sí àdírẹ́sì tí ó ṣe wẹ́kú nínú èyí tí a tò sí ojú ìwé 2.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]
Àwòrán rébété: Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.