ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 5/15 ojú ìwé 32
  • ‘Ọlọ́run ni Èmi Yóò Sá Di’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘Ọlọ́run ni Èmi Yóò Sá Di’
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 5/15 ojú ìwé 32

‘Ọlọ́run ni Èmi Yóò Sá Di’

NÍ “ÀWỌN àkókò líle koko tí ó nira láti bá lò” wọ̀nyí, àdánwò àti wàhálà túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Fún àpẹẹrẹ, a lè dán ìwà àìlábòsí wa wò ní ibi iṣẹ́. A lè dán ìwà funfun wa wò láàárín àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ wa. Ayé oníwà ìbàjẹ́ sì lè dán ìwà títọ́ wa wò.—Tímótì Kejì 3:1-5.

Òǹkọ̀wé Bíbélì náà, Ásáfù, pẹ̀lú gbé ní àkókò kan tí ìwà ìbàjẹ́ gbilẹ̀. Àwọn kan lára àwọn alájọgbáyé rẹ̀ tilẹ̀ fi ìwà wọn tí inú Ọlọ́run kò dùn sí yangàn. Ásáfù kọ̀wé pé: “Ìgbéraga . . . ká wọn lọ́rùn bí ẹ̀wọ̀n ọ̀ṣọ́; ìwà ipá bò wọ́n mọ́lẹ̀ bí aṣọ. Wọ́n ń ṣẹ̀sín, wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ búburú ní ti ìnilára: wọ́n ń sọ̀rọ̀ láti ibi gíga.” (Orin Dáfídì 73:6, 8) Ìṣarasíhùwà yí ha wọ́pọ̀ bí?

Fún àwọn tí wọ́n fẹ́ láti ṣe ohun tí ó tọ́, irú ìwà bẹ́ẹ̀ ń kó ìrora ọkàn báni, ó tilẹ̀ ń múni rẹ̀ wẹ̀sì. Ásáfù kédàárò pé: “Ní gbogbo òwúrọ̀ ni a ń yọ mí lẹ́nu. Ó ṣòro ní ojú mi.” (Orin Dáfídì 73:14, 16) O lè ní irú ìmọ̀lára kan náà, má ṣe sọ̀rètí nù! Ó ṣeé ṣe fún Ásáfù láti kojú ìwà ibi ọjọ́ rẹ̀, ìwọ pẹ̀lú lè ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́. Ṣùgbọ́n lọ́nà wo?

Ásáfù wá mọ̀ pé ìdájọ́ òdodo tòótọ́ fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ohun tí a kò lè rí lábẹ́ ìṣàkóso aláìpé ti ẹ̀dá ènìyàn. (Orin Dáfídì 146:3, 4; Òwe 17:23) Nítorí náà, kàkà tí yóò fi máa fi àkókò rẹ̀ ṣíṣeyebíye, agbára rẹ̀, àti ohun ìní rẹ̀ ṣòfò, ní gbígbìyànjú láti wá nǹkan ṣe sí gbogbo ìwà ibi tí ó wà yí i ká, ó darí àfiyèsí rẹ̀ sórí ipò ìbátan rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run. Ásáfù polongo pé: “Ní tèmi, sísúnmọ́ Ọlọ́run dára fún mi. Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ni mo fi ṣe ibi ìsádi mi.”—Orin Dáfídì 73:28, NW.

Lónìí, àwọn tí ń lọ́wọ́ nínú okòwò bìrìbìrì sábà máa ń gbádùn àǹfààní nípa ti ara. Ọ̀pọ̀ tilẹ̀ lè fi fífojú tí wọ́n fojú tín-ínrín òfin Ọlọ́run lórí ìwà híhù yangàn. Ṣùgbọ́n wọn kì yóò borí láé. Ásáfù sọ pé: “Ìwọ gbé wọn ka ibi yíyọ̀: ìwọ tì wọ́n ṣubú sínú ìparun.”—Orin Dáfídì 73:18.

Bẹ́ẹ̀ ni, nígbà tí àkókò bá tó lójú Ọlọ́run, ẹ̀tàn, ìwà ipá, ìwà ìbàjẹ́, àti àwọn ìwà míràn tí kò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu tí àwọn Kristẹni tòótọ́ gbọ́dọ̀ yẹra fún, kì yóò sí mọ́. Bíbélì ṣèlérí pé: “A óò ké àwọn olùṣe búburú kúrò: ṣùgbọ́n àwọn tí ó dúró de Olúwa ni yóò jogún ayé.” (Orin Dáfídì 37:9) Ní báyìí ná, ǹjẹ́ kí a lè sọ àwọn ọ̀rọ̀ onísáàmù náà ní àsọtúnsọ, ẹni tí ó wí pé: “Jèhófà ni àpáta gàǹgà mi àti odi agbára mi àti Olùpèsè àsálà fún mi. Ọlọ́run mi ni àpáta mi. Èmi yóò sá di í.”—Orin Dáfídì 18:2, NW.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́