Àìlábòsí—Ó Ha Ń Ṣèèṣì Wá Tàbí A Ń Ṣe Yíyàn Rẹ̀?
“BÍ N kò tilẹ̀ jẹ́ aláìlábòsí lọ́nà ti ẹ̀dá, mo máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan lọ́nà èèṣì.” Bí alábòsí ẹ̀dá, Autolycus, ti sọ nìyẹn, nínú ìwé The Winter’s Tale, láti ọwọ́ William Shakespeare. Èyí ṣàkàwé olórí àìlera ẹ̀dá ènìyàn—ìtẹ̀sí tí a ní sí ṣíṣe ohun tí kò tọ́, tí ń jẹyọ láti inú ‘ọkàn tí ó kún fún ẹ̀tàn.’ (Jeremáyà 17:9; Orin Dáfídì 51:5; Róòmù 5:12) Ṣùgbọ́n èyí ha túmọ̀ sí pé a kò ní yíyàn nínú ọ̀ràn yí bí? Ìwà funfun ha wulẹ̀ jẹ́ ọ̀ràn èèṣì bí? Rárá o!
Ṣáájú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wọ Ilẹ̀ Ìlérí, Mósè bá wọn sọ̀rọ̀ nígbà tí wọ́n pàgọ́ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù. Ó fi yíyàn méjì tí ó ṣe kedere síwájú wọn. Wọ́n lè ṣègbọràn sí àwọn àṣẹ Ọlọ́run, kí wọ́n sì rí ìbùkún rẹ̀ gbà tàbí kí wọ́n kọ̀ ọ́ sílẹ̀, kí wọ́n sì ká èso kíkan ti ẹ̀ṣẹ̀ wọn. (Diutarónómì 30:15-20) Yíyàn náà kù sọ́wọ́ wọn.
Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá olómìnira ìwà híhù, àwa pẹ̀lú ní yíyàn. Kò sí ẹnì kan—títí kan Ọlọ́run—tí ń fipá mú wa láti ṣe ohun rere tàbí ohun búburú. Ṣùgbọ́n, àwọn kan lè sọ pé, ‘Bí ọkàn àyà wa bá ń fà sí ṣíṣe ohun búburú, báwo ni a óò ṣe lè ṣe ohun rere?’ Tóò, olùtọ́jú eyín máa ń fara balẹ̀ yẹ eyín wò láti wá ìyìnrìn tàbí ìjẹrà kí ó tó lọ jìnnà jù. Bákan náà, a ní láti yẹ ọkàn àyà ìṣàpẹẹrẹ wa wò dáradára láti wá àìlera àti ìjẹrà ìwà híhù. Èé ṣe? Nítorí Jésù wí pé, “láti inú ọkàn àyà ni àwọn ìgbèrò burúkú ti ń wá, ìṣìkàpànìyàn, panṣágà, àgbèrè, olè jíjà, àwọn èké gbólóhùn ẹ̀rí, àwọn ọ̀rọ̀ òdì.”—Mátíù 15:18-20.
Láti tọ́jú eyín kan, olùtọ́jú eyín gbọ́dọ̀ ha ìjẹrà èyíkéyìí tí ó bá rí dànù. Bákan náà, a ní láti gbégbèésẹ̀ tìpinnutìpinnu láti ti “ìgbèrò burúkú” kúrò nínú ọkàn àyà wa. Nípa kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Bíbélì, àti ríronú lórí rẹ̀, kì í ṣe kìkì pé a óò wá mọ àwọn ọ̀nà Ẹlẹ́dàá wa nìkan ni, ṣùgbọ́n a óò tún kọ́ láti ṣe ohun tí ó tọ́.—Aísáyà 48:17.
Ọba Dáfídì ti Ísírẹ́lì lo ìrànwọ́ pípọn dandan mìíràn nínú jíjìjàkadì láti ṣe ohun tí ó tọ́. Ó gbàdúrà pé: “Dá àyà tuntun sínú mi, Ọlọ́run; kí o sì tún ọkàn dídúró ṣinṣin ṣe sínú mi.” (Orin Dáfídì 51:10) Bẹ́ẹ̀ ni, nípa gbígbára lé Jèhófà Ọlọ́run nínú àdúrà, àwa pẹ̀lú lè borí ìtẹ̀sí tí a ní láti ṣe ohun tí ó burú, kí a sì mú “ẹ̀mí tuntun” láti ṣe ohun tí ó tọ́ dàgbà. Lọ́nà yí, a kò ní fi àìlábòsí sílẹ̀ fún èèṣì. Yóò jẹ́ ọ̀ràn yíyàn.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Gẹ́gẹ́ bí ó ti rí nínú ọ̀ràn Dáfídì, àdúrà sí Jèhófà lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe rere