Nígbà Tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Bá Kàn Sí Ọ
Kí ni ó yẹ kí àwọn Kátólíìkì ṣe nígbà tí ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá kàn sí wọn nílé? Ìtẹ̀jáde tuntun kan, tí Ẹgbẹ́ Àwọn Katikíìsì Lápapọ̀ ti Ẹgbẹ́ Àwọn Bíṣọ́ọ̀bù ní Ítálì kọ sọ pé: “Fífi pẹ̀lẹ́ pùtù kọ̀ láti jíròrò, ṣùgbọ́n tí a ṣe lọ́nà tí kò gba gbẹ̀rẹ́, kì í ṣe àìmọ̀wàáhù rárá nínú ọ̀ràn yí.”
Kì í ṣe gbogbo Kátólíìkì ni ó gbà pẹ̀lú èyí, gẹ́gẹ́ bí lẹ́tà kan tí ọkùnrin kan tí ń gbé ní Foggia, Ítálì, fi ránṣẹ́ sí ilé iṣẹ́ ìwé agbéròyìnjáde Gazzetta del Mezzogiorno ti fi hàn:
“Èmi kì í ṣe ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Kátólíìkì ni mí. Ṣùgbọ́n àwọn òfin kan tí ṣọ́ọ̀ṣì ń gbé kalẹ̀ fún àwọn ọmọ ìjọ ń ṣe mí ní kàyéfì, ní sísọ fún wọn pé kí wọ́n lẹ àkọlé mọ́ ilẹ̀kùn wọn láti fi lé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ. Ó ṣe tán, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni àwọn ènìyàn wọ̀nyí ń wàásù rẹ̀, wọ́n sì ń ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ jíjinlẹ̀ sí i nípa Bíbélì. Èyí mú mi rántí ìgbà tí àrùn onígbá méjì kọ lu Ítálì, tí a sì fún wa nímọ̀ràn lórí bí a ṣe lè yẹra fún kíkó àrùn náà.
“Lójú ìwòye tèmi, èyí ń fi hàn pé ṣọ́ọ̀ṣì ń gbé àwọn òfin rẹ̀ kalẹ̀ láìgbé ohun tí àwọn ọmọ ìjọ ń fẹ́ yẹ̀ wò. Ṣùgbọ́n fún àwọn ọdún bíi mélòó kan nísinsìnyí, mo ti ń rí i pé àwọn Kátólíìkì pàápàá ti ń lọ láti ilé dé ilé, ní ṣíṣèbẹ̀wò sí ilé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pẹ̀lú; wọ́n sì ń gbà wọ́n wọlé, wọ́n ń jíròrò pẹ̀lú wọn, láìlé ẹnikẹ́ni lọ.”
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í fi dandan mú àwọn ènìyàn láti tẹ́wọ́ gba ìhìn iṣẹ́ wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń làkàkà láti ṣàjọpín ìrètí tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nawọ́ rẹ̀ jáde, tí ó ń tu àwọn fúnra wọn nínú ní àwọn àkókò onídààmú wọ̀nyí, pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Nípa lílọ láti ilé dé ilé, àti nípa bíbá àwọn tí wọ́n ṣalábàápàdé ní òpópónà sọ̀rọ̀, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣàjọpín ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run pẹ̀lú àwọn tí ó ṣe tán láti tẹ́tí sílẹ̀.—Mátíù 24:14; Ìṣe 5:42; 17:17.