“Òtítọ́ Ṣíṣeyebíye”
“Òtítọ́ ṣíṣeyebíye.” Bí lẹ́tà kan tí a kọ sí ẹ̀ka Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Nàìjíríà ṣe ṣàpèjúwe àwọn ìwé ìròyìn àrà ọ̀tọ̀ méjì kan nìyẹn. Òǹkọ̀wé náà, ọ̀dọ́mọkùnrin kan, ṣàlàyé pé:
“Mo ń kọ̀wé láti sọ ọpẹ́ àtọkànwá mi jáde fún ìsapá yín lórí sísọ̀rọ̀ nípa ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo apá ìgbésí ayé ojoojúmọ́ nípasẹ̀ ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí!
“Ọmọ ọdún 17 ni mí. Ní èṣí, ilé iṣẹ́ rédíò kan ládùúgbò wa gbé ìdíje àròkọ kan kalẹ̀ lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ náà ‘Ohun Tí Ń Bẹ Nínú Ọ̀rọ̀ Ìfẹ́ Ju Ọ̀ràn Ìbálòpọ̀ Lọ—Àrùn AIDS Ń Bẹ.’ Àròkọ kọ̀ọ̀kan kò gbọ́dọ̀ dín ní irínwó ọ̀rọ̀. Ẹni tí ó bá kọ àròkọ tí ó dára jù lọ yóò gba ẹ̀bùn 1,000 náírà [$12.50, U.S.]. Àmọ́, wọ́n sọ pé, kí àwọn ènìyàn má kọ àròkọ náà nítorí ète àtigbẹ̀bùn nìkan, ṣùgbọ́n, láti lè rí ẹ̀kọ́ kọ́. . . .
“Mo rí ìsọfúnni nípa àrùn AIDS nínú ìwé ìròyìn méjèèjì. Lórí ọ̀rọ̀ ìfẹ́, àpilẹ̀kọ tí ó wà lórí rẹ̀ pọ̀ lọ jàra. Mo lo àwọn kókó inú Jí! August 8, 1978 (Gẹ̀ẹ́sì).
“Nǹkan bí oṣù méjì lẹ́yìn tí mo fi àròkọ náà ránṣẹ́, èsì rẹ̀ jáde. Sí ìyàlẹ́nu mi, mo ṣe ipò kíní ní ìpínlẹ̀ Cross River àti Akwa Ibom!
“Inú àwọn ìwé ìròyìn yẹn ni mo ti rí gbogbo ìsọfúnni tí mo lò. Ó jẹ́ ohun àgbàyanu ní tòótọ́ pé Jèhófà ń pèsè ìsọfúnni àsìkò fún wa nínú ayé onídààmú àti aláìsàn yí. Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni tòótọ́, a mọ̀ pé ohun tí ń bẹ nínú ọ̀rọ̀ ìfẹ́ ju ọ̀ràn ìbálòpọ̀ lọ fíìfíì. Dájúdájú, gbígbé ìgbésí ayé mímọ́ ní ti ìwà híhù ń dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ àwọn àrùn bí AIDS.
“Mo dúpẹ́ mo tọ́pẹ́ dá fún àwọn òtítọ́ ṣíṣeyebíye wọ̀nyí tí ẹ ń pèsè láìṣàárẹ̀. Ǹjẹ́ kí Jèhófà túbọ̀ máa bù kún ìsapá yín bí ẹ ti ń bá a nìṣó ní pípèsè àwọn ìwé ìròyìn ṣíṣeyebíye wọ̀nyí.”