Ìwé Rẹpẹtẹ!
Ọlọgbọ́n Ọba Sólómọ́nì ìgbàanì kọ̀wé pé: “Nínú kíkọ ìwé púpọ̀, òpin kò sí.” (Oníwàásù 12:12) Ní 1995, ní ìpíndọ́gba, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìwé kan tí a ṣe fún ènìyàn 580 nínú àwọn olùgbé Britain, tí ó mú kí orílẹ̀-èdè yẹn di orílẹ̀-èdè tí ó mú ipò iwájú nínú títẹ ìwé tuntun jáde. China, orílẹ̀-èdè tí ó ní olùgbé jù lọ, wà ní ipò kejì pẹ̀lú 92,972 ẹ̀dà ní ìfiwéra pẹ̀lú 95,015 ti Britain. Germany tẹ̀ lé e (67,206 ìwé), lẹ́yìn náà ni United States (49,276), ti ilẹ̀ Faransé sì tẹ̀ lé e pẹ̀lú (41,234). Ìwé agbéròyìnjáde ti London, The Daily Telegraph, sọ pé: “Èdè Gẹ̀ẹ́sì ni ó mú kí Britain ṣáájú gbogbo ayé.”
Ìròyìn fi hàn pé, ọjà ìwé títà ti ń lọ sílẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún, nísinsìnyí, kìkì ìpín 80 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn àgbàlagbà ará Britain ní ń ra ìwé kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lọ́dọọdún. Ṣùgbọ́n gbogbo ìwé tí àwọn ènìyàn ń rà ni wọ́n ń kà bí?
Ìwé kan tí a ń bá a nìṣó láti pín kiri lọ́nà gbìgbòòrò jù lọ, tí a sì tí ì kà jù lọ ni Bíbélì, tí ó wà nísinsìnyí ní apá kan tàbí lódindi ní èdè tí ó lé ní 2,120. Bí o kò bá tí ì ní ẹ̀dà tìrẹ, kàn sí ọ́fíìsì Watch Tower Society tí ó sún mọ́ ọ jù lọ láti gba ẹ̀dà kan. Bí o bá ní Bíbélì, mú un jáde, kí o sì ṣí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a tọ́ka sí, tí ó fara hàn nínú àwọn àpilẹ̀kọ inú ìwé ìròyìn yí. Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò ṣàwárí ìmọ̀ tí ń fúnni ní ìyè tí Bíbélì ń fúnni.