ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 8/15 ojú ìwé 32
  • Wọ́n Dúró Gbọn-in Lójú Inúnibíni Ìjọba Nazi

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wọ́n Dúró Gbọn-in Lójú Inúnibíni Ìjọba Nazi
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 8/15 ojú ìwé 32

Wọ́n Dúró Gbọn-in Lójú Inúnibíni Ìjọba Nazi

ÌWÀ títọ́ aláìṣojo tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi hàn lábẹ́ ìjọba Nazi ti Germany yàtọ̀ gédégbé sí ipò tí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kirisẹ́ńdọ̀mù dì mú. Ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìtàn, John Weiss, ni ó sọ èyí nínú ìwé rẹ̀, Ideology of Death. Ó kọ̀wé pé:

“Ní 1934 ṣọ́ọ̀ṣì Evangelical fàáké kọ́rí pé ‘àwọn ẹlẹ́sìn Luther’ gbọ́dọ̀ ‘fi tayọ̀tayọ̀ tẹ́wọ́ gba’ ìjọba Nazi, kí wọ́n sì dúpẹ́ lọ́wọ́ ‘Olúwa Ọlọ́run’ fún fífún àwọn ará Germany ní ‘aṣáájú tí ó nítara, tí ó sì ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé.’ . . . Bíṣọ́ọ̀bù Pùròtẹ́sítáǹtì kan kọ̀wé sí àlùfáà rẹ̀ pé, ‘Ọlọ́run ni ó rán [Hitler] sí wa.’” Weiss ń bá a lọ pé: “Ṣọ́ọ̀ṣì Methodist ti ilẹ̀ Germany . . . gbà pẹ̀lú Bíṣọ́ọ̀bù Dibelius pé Hitler ti gba Germany lọ́wọ́ ọ̀tẹ̀ àwọn Bolshevik tí ó rọ̀ dẹ̀dẹ̀, ní mímú àlàáfíà àti ìsọ̀kan wá . . . Ṣọ́ọ̀ṣì Mormon rọ àwọn mẹ́ńbà rẹ̀ pé títako Hitler jẹ́ títẹ òfin Mormon lójú.” Ó sì fi kún un pé: “A sọ fún àwọn Kátólíìkì pé ojúṣe ọlọ́wọ̀ ni láti ṣègbọràn sí ìjọba tuntun náà, ojúṣe tí a kò fawọ́ rẹ̀ sẹ́yìn àní lẹ́yìn ìgbà tí gbogbo ohun ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ tí ń ṣẹlẹ̀ ní ìlà oòrùn di mímọ̀ fún àwùjọ àlùfáà.”

Ṣùgbọ́n Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ńkọ́? Ọ̀jọ̀gbọ́n Weiss tọ́ka sí i pé “gẹ́gẹ́ bí àwùjọ kan, kìkì Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n ta ko ìjọba Nazi.” A ju ẹgbẹẹgbẹ̀rún wọn sẹ́wọ̀n, Ọ̀jọ̀gbọ́n Weiss ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé, “síbẹ̀ à bá ti dá Ẹlẹ́rìí èyíkéyìí tí a rán lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ sílẹ̀, tí ó bá jẹ́ pé ó fọwọ́ sí ìwé pé òun sẹ́ ìgbàgbọ́ òun.”

Nípa ìwà títọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Weiss sọ pé: “Àpẹẹrẹ wọn ṣàkàwé bí àwọn Kristẹni ìjímìjí ṣe jẹ́ adúrógbọn-in lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ àti bí wọ́n ṣe jẹ́ akọni tó, kí ó tó di pé ètò ìsìn àti ìfarajìn fún ètò ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà bo ìfẹ́ ọkàn láti gbé ìgbésí ayé aláìfìgbàgbọ́ ẹni báni dọ́rẹ̀ẹ́ mọ́lẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí pásítọ̀ Pùròtẹ́sítáǹtì kan ṣe kọ̀wé nípa wọn, ‘Kì í ṣe àwọn ṣọ́ọ̀ṣì kàǹkà kàǹkà ni ó kọ́kọ́ dúró gbọn-in lòdì sí ìbínú ìjọba elèṣù Nazi, tí wọ́n sì gbójúgbóyà láti ṣàtakò ní ìbámu pẹ̀lú ìgbàgbọ́ wọn, bí kò ṣe àwọn ènìyàn tí a bà lórúkọ jẹ́, tí a sì bẹnu àtẹ́ lù wọ̀nyí.’”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́