Ìlérí Ta ni Ìwọ Lè Gbára Lé?
LỌ́DÚN 1893 àwùjọ àwọn 74 tí wọ́n jẹ́ ògbógi lórí ọ̀ràn ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà pàdé níbi Ìpàtẹ Ọjà Àgbáyé, ní Chicago, láti jíròrò nípa ọjọ́ ọ̀la. (Àwòrán ibẹ̀ ni a fi hàn lókè yí.) Ní wíwo 100 ọdún síwájú, ọdún 1993, díẹ̀ nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí wọ́n sọ nìyí: “Ọ̀pọ̀ ènìyàn yóò lè gbé ayé fún 150 ọdún.” “Ọgbà ẹ̀wọ̀n yóò dín kù, a kò sì ní ka ìkọ̀sílẹ̀ sí ohun tí a nílò mọ́.” “Ọ̀nà ìṣèjọba yóò rọrùn sí i, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé, bí nǹkan bá ṣe rọrùn tó ní ń fi hàn bí orílẹ̀-èdè kan ti dáńgájíá tó ní tòótọ́.”
Bákan náà, ní ọdún 1967, ìwé kan tí a pè ní The Year 2000 sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Nígbà tí yóò bá fi di ọdún 2000, kọ̀ǹpútà yóò ti fẹ́rẹ̀ẹ́ bá díẹ̀ nínú ọgbọ́n ‘ẹ̀dá ènìyàn’ dọ́gba, tàbí kí ó ti ní ọgbọ́n tí ó tó ti ẹ̀dá ènìyàn, tàbí kí ó ti ré kọjá rẹ̀, títí kan àwọn ọgbọ́n ìṣọnà àti ìhùmọ̀ rẹ̀.” “Èrò fífi àwọn róbọ́ọ̀tì tí kò wọ́n púpọ̀ ṣiṣẹ́ tí ó pọ̀ jù lọ nínú ilé . . . dà bí ohun tí yóò ṣeé ṣe nígbà tí yóò bà fi di ọdún 2000.”
Agbára tí aráyé kò ní láti mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la jẹ́ òdì kejì pátápátá sí agbára Ọlọ́run. Fún àpẹẹrẹ, fi àwọn ìsọtẹ́lẹ̀ tí a mẹ́nu kàn lókè yí wé ohun tí Bíbélì sọ ní nǹkan bí 20 ọ̀rúndún sẹ́yìn nípa ọjọ́ wa: “Àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, ajọra-ẹni-lójú, onírera, asọ̀rọ̀-òdì, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin, aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, afinihàn, olùwarùnkì, awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga, olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run, àwọn tí wọ́n ní àwòrán ìrísí ìfọkànsin Ọlọ́run ṣùgbọ́n tí wọ́n jásí èké ní ti agbára rẹ̀.”—Tímótì Kejì 3:1-5.
Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì yí nípa “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” wulẹ̀ jẹ́ ọ̀kan ṣoṣo péré nínú àwọn èyí tí ó ti ní ìmúṣẹ ní ọjọ́ wa. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ pé “àmì” wíwàníhìn-ín Jésù yóò ní, ogun, àìtó oúnjẹ, àjàkálẹ̀ àrùn, ìsẹ̀lẹ̀, àti ìwàásù kárí ayé nípa ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run nínú.—Mátíù 24:3-14; Lúùkù 21:11.
Àìlètàsé ìlérí Ọlọ́run sún ọ̀kan lára àwọn tí ó kọ Bíbélì láti polongo ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn pé: “Kò sí ohun kan tí ó tàsé nínú ohun rere gbogbo tí OLÚWA Ọlọ́run yín ti sọ ní ti yín; gbogbo rẹ̀ ni ó ṣẹ fún yín, kò sí ohun tí ó tàsé nínú rẹ̀.”—Jóṣúà 23:14.
Bẹ́ẹ̀ ni, a lè ní ìdánilójú pé gbogbo ìlérí Ọlọ́run yóò ṣẹ láìpẹ́. Ìjọba Ọlọ́run yóò mú òpin dé bá àìsàn, ìwà ọ̀daràn, ìjoògùnyó, ebi, àti ogun—gbogbo ilẹ̀ ayé yóò di párádísè. (Orin Dáfídì 37:10, 11 29; Ìṣípayá 21:3, 4) O lè gbọ́kàn lé ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ yí! Ọ̀dọ̀ Ẹlẹ́dàá wa, “ẹni tí kò lè purọ́,” ni ó ti wá.—Títù 1:2; fi wé Hébérù 6:13-19.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]
Cleveland State University Archive