Ìgbéyàwó Tí Kò Ní Ète Ìbálòpọ̀ Nínú Ha Ni Bí?
NÍNÚ ìgbìdánwò láti so èrò pé Màríà wà ní wúńdíá títí lọ kánrin mọ́ ìgbéyàwó tí òun pẹ̀lú Jósẹ́fù ṣe, ọ̀pọ̀ ayàwòrán àti oníṣọ̀nà ti ya Jósẹ́fù gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin kan tí ó darúgbó. Wọ́n ronú pé, Jósẹ́fù kò ṣe bí ọkọ fún Màríà rárá, àfi bí alágbàtọ́ rẹ̀. Ṣùgbọ́n Póòpù John Paul Kejì láìpẹ́ yìí ṣalágbàwí ojú ìwòye mìíràn nípa ọ̀ràn náà. Ó sọ pé, Jósẹ́fù “kì í ṣe arúgbó ní àkókò náà.” Kàkà bẹ́ẹ̀, “ìjẹ́pípé rẹ̀ ti inú lọ́hùn-ún, èso oore ọ̀fẹ́, sún un láti fi ìfẹ́ni tí kò ní ète ìbálòpọ̀ nínú gbé ìgbésí ayé lọ́kọláya pẹ̀lú Màríà.”
Bí Màríà bá fẹ́ wà ní wúńdíá títí ayérayé, èé ṣe tí ó fi ní àfẹ́sọ́nà? Póòpù fèsì pé: “A lè gbà pé nígbà tí àwọn méjèèjì jọ́hẹn fúnra wọn, Jósẹ́fù àti Màríà fohùn ṣọ̀kan nípa ìwéwèé náà láti gbé gẹ́gẹ́ bí wúńdíá.”
Ṣùgbọ́n, Bíbélì gbé ọ̀ràn náà kalẹ̀ lọ́nà tí ó yàtọ̀. Àkọsílẹ̀ Mátíù sọ pé, Jósẹ́fù “kò bá a ṣe títí tí ó fi bí ọmọkùnrin kan.” (Mátíù 1:25, New American Bible ti Kátólíìkì, ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.) Lẹ́yìn ìbí Jésù, ìdè ìgbéyàwó àárín Jósẹ́fù àti Màríà kì í ṣe èyí tí kò ní ète ìbálòpọ̀ nínú rárá. Ẹ̀rí kan nípa èyí ni pé níwájú nínú àkọsílẹ̀ Ìhìn Rere, a sọ pé Jésù ní àwọn arákùnrin àti arábìnrin.—Mátíù 13:55, 56.
Nípa báyìí, bí Bíbélì tilẹ̀ sọ pé Màríà jẹ́ wúńdíá nígbà tí ó bí Jésù, kò sí ẹ̀rí fún sísọ pé ó gbé gẹ́gẹ́ bíi wúńdíá jálẹ̀ ìyókù ìgbésí ayé rẹ̀ pẹ̀lú Jósẹ́fù.