Wọ́n Ń yin Ẹlẹ́dàá Wọn Láìfọhùn
LỌ́NÀ ti ẹ̀dá, wíwọ̀ oòrùn jẹ́ àrímáleèlọ. Ṣùgbọ́n rírí bí oòrùn ti ń wọ̀ ní ẹ̀yìn òkè ńlá yìí ní Òkè Apuan ti Tuscany, Ítálì, tún yàtọ̀ pátápátá.
Bí a bá wò ó láti òkèèrè, yóò dà bíi pé oòrùn náà já bọ́ sórí òkè náà dípò wíwọ̀ sẹ́yìn rẹ̀. Èé ṣe? Nítorí pé lọ́nà tí a gbà dá a, orí òkè náà jin kòtò, tí ó mú kí ó jọ pé ṣe ni a gbẹ́ ẹ jáde kúrò lára òkè náà. Ní tòótọ́, òkìtì yí ti gba orúkọ rẹ̀, Monte Forato—Òkè Oníhò. Nítorí bí ilẹ̀ ayé ṣe ń yí oòrùn po, ìgbà méjì péré láàárín ọdún ni àwọn tí ń wo ibi jíjin kòtò náà lè rí oòrùn tí ó dà bíi pé ó fẹ́ já bọ́ sínú òkè Monte Forato.
Bí àwọn apá fífanimọ́ra mìíràn nínú ìṣẹ̀dá, àwọn ohun aláìlẹ́mìí lójú ọ̀run ń yin Ẹlẹ́dàá wọn. Lọ́nà wo? Lọ́nà kan náà tí àwòrán rèǹtè rente kan fi lè mú ìyìn wá fún ayàwòrán tí ó yà á. Ní ti gidi, àwọn ohun tí ń bẹ lójú ọ̀run ń sọ nípa agbára, ọgbọ́n, àti ìtóbilọ́lá Jèhófà. Gẹ́gẹ́ bí onísáàmù náà ti sọ ọ́, “àwọn ọ̀run ń sọ̀rọ̀ ògo Ọlọ́run: àti òfuurufú ń fi iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ hàn.” (Orin Dáfídì 19:1; 69:34) Níwọ̀n bí oòrùn àti àwọn ohun aláìlẹ́mìí mìíràn ti ń yin Ẹlẹ́dàá wọn, ẹ wo bí ó ti yẹ tó pé kí àwa pẹ̀lú ṣe bẹ́ẹ̀!—Orin Dáfídì 148:1, 3, 12, 13.