“Òun Ni Májẹ̀mú Tuntun Alápapọ̀ Èdè Méjì Dídára Jù Lọ Tí Ó Wà Lárọ̀ọ́wọ́tó”
BÍ Ọ̀MỌ̀WÉ Jason BeDuhn ṣe ṣàpèjúwe The Kingdom Interlinear Translation of the Greek Scriptures nìyẹn. Ó ṣàlàyé pé:
“Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ parí kíkọ́ni ní ẹ̀kọ́ ní Ẹ̀ka Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìsìn ní Yunifásítì Indiana, Bloomington, [U.S.A.] ni . . . Èyí ní pàtàkì jẹ́ ẹ̀kọ́ lórí àwọn Ìhìn Rere. Ìrànwọ́ yín wá nípasẹ̀ àwọn ẹ̀dà The Kingdom Interlinear Translation of the Greek Scriptures tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mi lò gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ìwé àkànlò fún kíláàsì náà. Àwọn ìdìpọ̀ kéékèèké yìí ṣeyebíye fún ètò ẹ̀kọ́ náà, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mi sì mọ̀ ọ́n bí ẹní mowó.”
Èé ṣe tí Ọ̀mọ̀wé BeDuhn fi lo ìtumọ̀ Kingdom Interlinear nínú ètò ẹ̀kọ́ kọ́lẹ́ẹ̀jì rẹ̀? Ó dáhùn pé: “Ká sọ ọ́ lọ́nà tí ó rọrùn, òun ni Májẹ̀mú Tuntun alápapọ̀ èdè méjì dídára jù lọ tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó. Mo jẹ́ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ lórí Bíbélì, mo mọ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ àti àwọn irinṣẹ́ tí a ń lò nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lóde òní dunjú, ó sì wá jẹ́ pé n kì í ṣe ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ṣùgbọ́n mo mọ ìtẹ̀jáde tí ó jẹ́ ojúlówó bí mo bá rí i, ‘Ìgbìmọ̀ Bíbélì ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun’ tí ẹ ní sì ti ṣe iṣẹ́ rẹ̀ dáadáa. Ìtumọ̀ alápapọ̀ èdè méjì yín lédè Gẹ̀ẹ́sì péye, ó sì ṣe déédéé délẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi ń sún òǹkàwé láti ronú jinlẹ̀ nípa ìlò èdè, àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀, àti ìyàtọ̀ èrò tí ó wà láàárín ayé tí ń sọ èdè Gíríìkì àti tiwa. ‘Ìtumọ̀ Ayé Tuntun’ yín pegedé, ó jẹ́ ìtumọ̀ ṣangiliti tí ó yẹra fún àwọn àlàyé gẹ́gẹ́ bí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ní rírí i pé òun bá èdè Gíríìkì mu. Lọ́nà púpọ̀, ó níye lórí ju ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ tí ó wọ́pọ̀ jù lọ tí a ń lò lónìí.”
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ó tẹ The Kingdom Interlinear Translation of the Greek Scriptures jáde láti ran àwọn olùfẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́wọ́ láti dojúlùmọ̀ àwọn ẹsẹ Bíbélì ní èdè Gíríìkì àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀. Ó ní The New Testament in the Original Greek, ní apá òsì ojú ìwé náà (tí B. F. Westcott àti F. J. A. Hort kó jọ). Ìtumọ̀ ṣangiliti ti ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́sì kọ̀ọ̀kan wà lábẹ́ ìlà ẹsẹ ti èdè Gíríìkì. Ní ìlà tín-ínrín lápá ọ̀tún ni Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun wà, tí ó mú kí ó ṣeé ṣe fún ọ láti fi ìtumọ̀ ti alápapọ̀ èdè méjì wé ìtumọ̀ Bíbélì ní èdè Gẹ̀ẹ́sì ti òde òní.