Àwọn Dókítà, Adájọ́, àti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà
NÍ March ọdún 1995, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣonígbọ̀wọ́ àpérò méjì ní Brazil. Kí ni ète rẹ̀? Láti wá ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ ìṣègùn àti amòfin nígbà tí ẹni tí ń gbàtọ́jú ní ilé ìwòsàn bá jẹ́ ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí kò sì fẹ́ gba ẹ̀jẹ̀ sára.—Ìṣe 15:29.
Ó bani nínú jẹ́ pé, nínú àwọn ọ̀ràn kan, àwọn dókítà ti pa ìfẹ́ ọkàn Àwọn Ẹlẹ́rìí tí ń gbàtọ́jú tì, wọ́n sì ti lọ gba àṣẹ ilé ẹjọ́ láti fipá fa ẹ̀jẹ̀ sí wọn lára. Nínú irú àwọn ipò bẹ́ẹ̀, Àwọn Ẹlẹ́rìí ti lo ọ̀nà òfin èyíkéyìí tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó wọn láti dáàbò bo ara wọn. Síbẹ̀síbẹ̀, wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí fífọwọ́sowọ́pọ̀ ju gbígbéjà koni lójú lọ. Nípa báyìí, àwọn àpérò náà tẹnu mọ́ ọn pé ọ̀pọ̀ nǹkan wà tí a lè ṣe dípò fífa ẹ̀jẹ̀ ẹlòmíràn tí ó bá tẹni mu síni lára fún ìtọ́jú ìṣègùn àti pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ́wọ́ gba ìwọ̀nyí tayọ̀tayọ̀.a
Ṣáájú àkókò yìí, ìpàdé Ìgbìmọ̀ Ìṣègùn Ẹlẹ́kùnjẹkùn ti São Paulo ti fọwọ́ sí ipò tí Àwọn Ẹlẹ́rìí dì mú. Ní January ọdún 1995, ó pinnu pé, bí agbàtọ́jú kan kò bá fẹ́ ìtọ́jú tí dókítà kan fẹ́ lò, ó lẹ́tọ̀ọ́ láti kọ̀ ọ́, kí ó sì yan dókítà mìíràn.
Lọ́nà tí ó yẹ fún oríyìn, ọgọ́rọ̀ọ̀rún dókítà ń bẹ láwùjọ àwọn oníṣègùn ilẹ̀ Brazil nísinsìnyí, tí wọ́n ṣe tán láti lo ọ̀nà ìtọ́jú tí kò mú ìlò ẹ̀jẹ̀ lọ́wọ́ fún àwọn tí ó ń gbàtọ́jú tí ó bá fẹ́ ẹ. Láti ìgbà àwọn àpérò tí a ṣe ní March ọdún 1995 náà, ìfọwọ́sowọ́pọ̀ láàárín àwọn dókítà, adájọ́, àti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Brazil ti sunwọ̀n sí i lọ́nà tí ó jọni lójú. Ní ọdún 1997, ìwé ìròyìn ìṣègùn ti ilẹ̀ Brazil náà, Âmbito Hospitalar, gbé àpilẹ̀kọ kan jáde tí ó rin kinkin mọ́ bíbọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní láti di ipò tí wọ́n dì mú mú lórí ọ̀ràn ẹ̀jẹ̀. Ó ti wá di mímọ̀ káàkiri nísinsìnyí pé, gẹ́gẹ́ bí Ìgbìmọ̀ Ìṣègùn Ẹlẹ́kùnjẹkùn ti sọ fún ìpínlẹ̀ Rio de Janeiro àti São Paulo, “ojúṣe dókítà láti gba ẹ̀mí ẹni tí ń gbàtọ́jú lọ́dọ̀ rẹ̀ là kò gbọ́dọ̀ ga ju ojúṣe rẹ̀ láti gbèjà ẹ̀tọ́ agbàtọ́jú náà láti ṣe yíyàn.”
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ìsọfúnni kíkún sí i, wo ìwé pẹlẹbẹ náà, How Can Blood Save Your Life?, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.