A Gbóṣùbà fún Àpéjọpọ̀ “Àrà Ọ̀tọ̀”
AKÉDE kan lórí rédíò kan ní Lima, Peru, ń kọminú gidigidi nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ṣùgbọ́n, lẹ́yìn lílọ sí ọ̀kan lára àwọn àpéjọpọ̀ wọn, ẹ̀mí ìrònú rẹ̀ yí padà pátápátá. Ní tòótọ́, ó wú u lórí tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi sọ àwọn ọ̀rọ̀ rere nípa wọn fún àwọn olùgbọ́ rẹ̀ lórí rédíò. Díẹ̀ nínú ohun tí ó sọ rèé:
“Àrà ọ̀tọ̀ gbáà ni àpéjọpọ̀ náà. Kò sí ẹyọ bébà kan nílẹ̀, kò sì sí àwọn olùtajà láyìíká ibẹ̀. Kò sí súnkẹrẹ-fàkẹrẹ ọkọ̀. Ẹ̀ẹ́dẹ́gbàata lé ní igba ni iye àwọn ènìyàn tí ó fowó ara wọn wọkọ̀ lọ sí pápá ìṣeré ìdárayá náà, ẹnì kọ̀ọ̀kan gbé korobá, wọ́n mú àkísà, ìnulẹ̀, ìkólẹ̀, ìgbálẹ̀, búrọ́ọ̀ṣì ìfọ-nǹkan, ìbọ̀wọ́, àti ọṣẹ lọ́wọ́, láti fọ ibẹ̀ mọ́ tónítóní. Ibikíbi tí ó yẹ ní kíkùn, wọ́n kùn ún. Ibo sì ni wọ́n ti rí owó? Ọwọ́ ara wọn ni! Nígbà tí wọ́n fi ohun tí ó yẹ láti ṣe tó wọn létí, kíá ni gbogbo wọn tọwọ́ bọ àpò láti fowó sílẹ̀. Ṣé ẹ rí i, Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì kò ráyè irú àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀. Ẹ mà ṣeun o ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti ẹ̀yin olùṣekòkáárí iṣẹ́ yìí. Mo sì ń sọ fún yín láti ọkàn mi wá pé, Ọlọ́run yóò máa ràn yín lọ́wọ́, yóò sì máa bù kún yín.”
Ní àwọn ìlú káàkiri ayé ní ọdún yìí, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò gbádùn Àpéjọpọ̀ Àgbègbè náà, “Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tí Ọlọ́run Fẹ́.” Ìwọ yóò ha wà níbẹ̀ bí?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 32]
“Kò sí ẹyọ bébà kan nílẹ̀”