Jọ̀wọ́ Dara Pọ̀ Mọ́ Wa Fún Ìṣẹ̀lẹ̀ Àkànṣe Kan Ní Saturday, April 11, 1998
ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ fi ayọ̀ ké sí ọ láti wá bá wọn ṣèrántí ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fi fúnni, Jésù Kristi, Ọmọ rẹ̀. Ẹ̀bùn yìí ni ó ṣí ọ̀nà ìrètí gbígbádùn ìyè àìnípẹ̀kun sílẹ̀ fún aráyé.—Jòhánù 3:16.
Ní ọdún yìí, a óò ṣe Ìṣe Ìrántí ikú Jésù ní Saturday, April 11, lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀. Ọjọ́ náà ṣe rẹ́gí pẹ̀lú Nísàn 14 ti kàlẹ́ńdà òṣùpá inú Bíbélì. Jọ̀wọ́ wádìí lọ́dọ̀ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ń bẹ ládùúgbò rẹ láti mọ ibi tí a óò ti ṣe é àti àkókò náà gan-an tí yóò wáyé.