‘Láti Ìgbà Ọmọdé Jòjòló Ni Ìwọ Ti Mọ̀’
GẸ́GẸ́ bí ìwádìí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ti lọ́ọ́lọ́ọ́ ti sọ, bíbá àwọn ọmọdé jòjòló sọ̀rọ̀ ń nípa jíjinlẹ̀ lórí ìdàgbàsókè ọpọlọ wọn, ó ń fìdí agbára ìrònú wọn, òye wọn, àti agbára wọn láti yanjú ìṣòro múlẹ̀. Èyí ń rí bẹ́ẹ̀ ní pàtàkì ní ọdún àkọ́kọ́ ìgbésí ayé ìkókó kan. Ìwé ìròyìn International Herald Tribune sọ pé àwọn olùwádìí kan ti gbà nísinsìnyí pé “iye ọ̀rọ̀ tí ọmọdé jòjòló kan ń gbọ́ lójúmọ́ ni ohun títayọ tí ó ṣe pàtàkì jù lọ tí ń pinnu òye, àṣeyọrí ní ilé ẹ̀kọ́ àti ìdáńgájíá ní ti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà ọmọ náà lẹ́yìnwá ọ̀la.”
Ṣùgbọ́n, àwọn ọ̀rọ̀ àsọjáde náà gbọ́dọ̀ ti ẹnu ẹnì kan wá. A kò lè fi tẹlifísọ̀n tàbí rédíò rọ́pò.
Onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ètò iṣan ara ní Yunifásítì Washington ní Seattle, U.S.A., wí pé: “A ti wá mọ̀ pé ìgbà ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé ni a ti ń ṣètò àwọn ìsopọ̀ ètò iṣan ara àti pé ọpọlọ ọmọdé jòjòló ń dúró de ìrírí láti pinnu bí a óò ṣe ṣètò àwọn ìsopọ̀ ètò iṣan ara rẹ̀. Kò tí ì pẹ́ púpọ̀ nísinsìnyí tí a mọ bí ètò yìí ṣe tètè ń bẹ̀rẹ̀ tó. Fún àpẹẹrẹ, àwọn ọmọdé jòjòló ti kọ́ ìró ohùn èdè ìbílẹ̀ wọn ní ọmọ oṣù mẹ́fà.”
Ìwádìí tako èrò tí ó wọ́pọ̀ pé, àwọn ìkókó yóò dàgbà dáadáa ní ti òye bí a bá wulẹ̀ fi ọ̀pọ̀ ìfẹ́ hàn sí wọn. Ó tún tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì ipa àwọn òbí nínú ìdàgbàsókè ọmọ.
Èyí rán wa létí àwọn ọ̀rọ̀ lẹ́tà onímìísí tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí Tímótì pé: “Láti ìgbà ọmọdé jòjòló ni ìwọ ti mọ ìwé mímọ́, èyí tí ó lè sọ ọ́ di ọlọ́gbọ́n fún ìgbàlà.” Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé ìwé mímọ́, tí ìyá Tímótì àti ìyà rẹ̀ àgbà tí wọ́n jẹ́ onígbàgbọ́ kà fún un, kó ipa pàtàkì nínú ìdàgbàsókè rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí ó tayọ lọ́lá.—2 Tímótì 1:5; 3:15.