ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 8/1 ojú ìwé 32
  • Èé Ṣe Tí O Kò Fi Wà Pẹ̀lú Wọn?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Èé Ṣe Tí O Kò Fi Wà Pẹ̀lú Wọn?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 8/1 ojú ìwé 32

Èé Ṣe Tí O Kò Fi Wà Pẹ̀lú Wọn?

ẸNI ọdún 73 ni Ndjaukua Ulimba, ó sì rin ìrìn àjò tí ó tó 450 kìlómítà ní ọdún tí ó kọjá. Ẹsẹ̀ ni ó fi rin gbogbo rẹ̀, ó sì gbà á ní ọjọ́ 16.

Ọkùnrin arúgbó ọmọlúwàbí yìí rin ìrìn àjò gígùn náà kí ó bàa lè wà ní ọ̀kan nínú àwọn àpéjọpọ̀ ọdọọdún ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lẹ́yìn àpéjọpọ̀ náà, inú rẹ̀ dùn jọjọ, ó sì ti rí okun nípa tẹ̀mí gbà, ó tún fẹsẹ̀ rìn padà sílé—ó gbà á ní ọjọ́ 16 mìíràn. Ó ha yẹ kí ó ṣe ìsapá yìí bí? Bẹ́ẹ̀ ni, ó yẹ kí ó ṣe bẹ́ẹ̀! Fún ọdún mélòó kan, bí Ndjaukua Ulimba ṣe ń rin ìrìn àjò náà lọ́dọọdún nìyẹn.

Ọkùnrin ará Áfíríkà yìí jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí ó lé ní mílíọ̀nù 15 láti ilẹ̀ tí ó lé ní 230, tí wọ́n lọ sí àwọn àpéjọpọ̀ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní èṣí. Àmọ́ ṣáá o, ọ̀pọ̀ jù lọ wọn kò ní láti fẹsẹ̀ rìn fún ọ̀pọ̀ ọjọ́ kí wọ́n tó dé ọ̀gangan àpéjọpọ̀. Ọ̀pọ̀ jù lọ wọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, bọ́ọ̀sì, ọkọ̀ ojú irin, tàbí ti òfuurufú. Ìwọ ha jẹ́ ọ̀kan nínú wọn bí?

Ní ọdún 1998, a óò tún ṣe àwọn àpéjọpọ̀ káàkiri àgbáyé, ọ̀pọ̀ jù lọ yóò jẹ́ ní àwọn oṣù ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn. Bí àjíǹde ara bá jẹ́, ó ṣeé ṣe kí Ndjaukua Ulimba tún fẹsẹ̀ rin ọ̀nà jíjìn kí ó bàa lè wà níbẹ̀. Òun àti àràádọ́ta ọ̀kẹ́ mìíràn yóò gbọ́ ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí o gbéṣẹ́, tí ó ń fún ìgbàgbọ́ lókun, tí ó sì ń tani jí. Ohun mánigbàgbé nínú ọdún ni àpéjọpọ̀ náà yóò jẹ́ fún gbogbo àwọn tí ó bá lọ. A fi ọ̀yàyà ké sí ìwọ pẹ̀lú láti wà níbẹ̀. Inú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ń bẹ ládùúgbò rẹ yóò dùn láti sọ ọ̀gangan tí wọn yóò ti ṣe àpéjọpọ̀ tí ó sún mọ́ ọ jù lọ fún ọ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́