Ìwà Rere Ń Mú Ìyìn Wá
ÌWÉ ìròyìn èdè Italian náà, La Gazzetta del Mezzogiorno, gbóríyìn fún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún títẹ àpilẹ̀kọ náà, “Matera—Ìlú Ńlá Àwọn Ibùgbé Inú Hòrò Ṣíṣàrà-Ọ̀tọ̀,” jáde. Àpilẹ̀kọ yìí fara hàn nínú ìwé ìròyìn Jí! ti July 8, 1997, tí a pín kiri lọ́nà gbígbòòrò ní ọ̀pọ̀ èdè. Ní lọ́ọ́lọ́ọ́, a ń túmọ̀ Jí! sí èdè 81, a sì ń pín iye tí ó lé ní mílíọ̀nù 19 kiri kárí ayé. Ìwé ìròyìn náà sọ pé, Jí! jẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn yìí “tí ó bá di lílukoro ìtàn àti iṣẹ́ ọnà àbáláyé ti ìlú [Matera] jáde fáyé gbọ́.”
Ìwé ìròyìn náà gbóríyìn fún Àwọn Ẹlẹ́rìí nípa Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ìgbàgbọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” tí wọ́n ṣe ní Matera ní ọdún 1997. Àpilẹ̀kọ náà sọ pé, Àwọn Ẹlẹ́rìí gbìyànjú “láti rí 4,000 ènìyàn tí ó wá sí Pápá Ìṣeré Settembre Kọkànlélógún ti [ìlú náà] ní àárín ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn àti lábẹ́ oòrùn tí ó mú janjan; wọ́n gbá ibẹ̀ mọ́ tónítóní, wọ́n tún un kùn, wọ́n sì mú ojúkò eré ìdárayá yìí sunwọ̀n sí i (ní pàtàkì àwọn ilé ìgbọ̀nsẹ̀) láìbéèrè kọ́bọ̀, owó ara wọn ni wọ́n fi ra àwọn ohun kòṣeémánìí tí wọ́n lò níbẹ̀.”
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbìyànjú láti jẹ́ aládùúgbò rere. (Mátíù 22:37-39) Wọ́n tún ń tẹ̀ lé ìṣílétí tí ó wà nínú Ìwé Mímọ́ pé: “Ẹ tọ́jú ìwà yín kí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, pé, nínú ohun náà tí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ lòdì sí yín gẹ́gẹ́ bí aṣebi, kí wọ́n lè tipa àwọn iṣẹ́ yín àtàtà tí wọ́n fojú rí, yin Ọlọ́run lógo ní ọjọ́ náà fún àbẹ̀wò rẹ̀.”—1 Pétérù 2:12.