ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 8/15 ojú ìwé 30
  • Ìwọ Ha Rántí Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìwọ Ha Rántí Bí?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ni Ọjọ́ Ìdájọ́?
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Ọjọ́ Ìdájọ́ Ọlọ́run—Àbájáde Rẹ̀ Aláyọ̀!
    Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
  • “Àyànfẹ́ Mi, Ẹni Tí Ọkàn Mi Tẹ́wọ́ Gbà!”
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
  • Fara Wé Jèhófà—Máa Ṣe Òdodo àti Ìdájọ́ Òdodo
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 8/15 ojú ìwé 30

Ìwọ Ha Rántí Bí?

Ǹjẹ́ o ti baralẹ̀ ronú lórí àwọn ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ lọ́ọ́lọ́ọ́? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, yóò dùn mọ́ ọ láti rántí àwọn nǹkan wọ̀nyí:

◻ Èé ṣe tí ẹ̀kọ́ àyànmọ́ kò fi bọ́gbọ́n mu?

Bí Ọlọ́run bá ti mọ̀ pé Ádámù yóò dẹ́ṣẹ̀, tí ó sì ti ṣàkọọ́lẹ̀ rẹ̀ bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé Jèhófà di orísun ẹ̀ṣẹ̀ nígbà tí ó dá ènìyàn, òun ni ó sì jẹ̀bi gbogbo ìwà burúkú àti ìjìyà ẹ̀dá ènìyàn. A kò lè mú èrò yìí bá òtítọ́ náà mu pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run ìfẹ́ àti ìdájọ́ òdodo tí ó kórìíra ìwà burúkú. (Sáàmù 33:5; Òwe 15:9; 1 Jòhánù 4:8)—4/15, ojú ìwé 7, 8.

◻ Ní ìmúṣẹ Aísáyà 2:2-4, kí ni àwọn ènìyàn tí ó ti inú ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè wá ń ṣe?

Bí wọ́n ti ń wọ́ tìrítìrí lọ sílé ìjọsìn Jèhófà, wọ́n tún ń yẹra fún ‘kíkọ́ṣẹ́ ogun’ nítorí pé wọ́n ti gbé ọkàn wọn lé ààbò ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run ti Ọlọ́run, tí ó ti wà ní sẹpẹ́ láti pa gbogbo ọ̀tá àlàáfíà run.—4/15, ojú ìwé 30.

◻ Àwọn wo ni àwọn alágbára ti Jèhófà tí a sọ̀rọ̀ wọn nínú Jóẹ́lì 3:10, 11?

Ní nǹkan bí 280 ìgbà nínú Bíbélì, a pe Ọlọ́run tòótọ́ náà ní “Jèhófà àwọn ọmọ ogun.” (2 Àwọn Ọba 3:14) Àwọn ọmọ ogun wọ̀nyí ni àwọn ògìdìgbó áńgẹ́lì ọ̀run, tí wọ́n múra tán láti mú ìfẹ́ Jèhófà ṣẹ.—5/1, ojú ìwé 23.

◻ Ẹ̀kọ́ wo ni a lè rí kọ́ nínú pé Jèhófà ní kí Jóòbù gbàdúrà fún àwọn tí ó ti ṣẹ̀ ẹ́? (Jóòbù 42:8)

Kí ara Jóòbù tó yá, Jèhófà ní kí ó gbàdúrà fún àwọn tí ó ti ṣẹ̀ ẹ́. Èyí fi hàn pé Jèhófà fẹ́ kí a dárí ji àwọn tí ó ṣẹ̀ wá, kí ó tó lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ tiwa náà jì wá. (Mátíù 6:12; Éfésù 4:32)—5/1, ojú ìwé 31.

◻ Kí ni Jákọ́bù ní lọ́kàn nígbà tí ó wí pé: “Ẹ jẹ́ kí ìfaradà ṣe iṣẹ́ rẹ̀ pé pérépéré”? (Jákọ́bù 1:4)

Ìfaradà ní “iṣẹ́” kan láti ṣe. Iṣẹ́ rẹ̀ ni láti mú wa pé pérépéré ní gbogbo ọ̀nà. Nítorí náà, bí a bá jẹ́ kí àwọn àdánwò ṣe iṣẹ́ wọn délẹ̀délẹ̀ láìgbìdánwò láti lo àwọn ọ̀nà tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu láti fòpin sí wọn lójijì, a óò dán ìgbàgbọ́ wa wò, a óò sì yọ́ ọ mọ́.—5/15, ojú ìwé 16.

◻ Kí ló fà á tí Ọlọ́run fi dúró pẹ́ tó báyìí láti yanjú àwọn ìṣòro aráyé?

Ojú ìwòye Jèhófà nípa àkókò yàtọ̀ sí tiwa. Lójú Ọlọ́run ayérayé, ìgbà tí a dá Ádámù títí di ìsinsìnyí kò tilẹ̀ tí ì tó ọ̀sẹ̀ kan. (2 Pétérù 3:8) Ṣùgbọ́n láìka ojú ìwòye tí a lè ní nípa àkókò sí, ọjọ́ kọ̀ọ̀kan tí ń kọjá ń mú wa sún mọ́ ọjọ́ ìdáláre Jèhófà.—6/1, ojú ìwé 5, 6.

◻ Kí ní ń sún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣiṣẹ́?

Ẹ̀kọ́ Jèhófà ti mú àwọn ènìyàn tí wọ́n yàtọ̀ gédégbé jáde, àwọn tí a kọ́ láti nífẹ̀ẹ́ ẹnì kíní kejì àti àwọn aládùúgbò wọn gẹ́gẹ́ bí ara wọn. (Aísáyà 54:13) Ìfẹ́ ni ó ń sún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti máa bá wíwàásù lọ láìka ẹ̀mí ìdágunlá tàbí inúnibíni sí. (Mátíù 22:36-40; 1 Kọ́ríńtì 13:1-8)—6/15, ojú ìwé 20.

◻ Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé: “Ẹ tiraka tokuntokun láti gba ẹnu ọ̀nà tóóró wọlé”? (Lúùkù 13:24)

Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ túmọ̀ sí lílàkàkà, lílo ara ẹni. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tún fi hàn pé àwọn kan lè wá ọ̀nà láti ‘gba ẹnu ọ̀nà náà wọlé’ ní kìkì àkókò tí ó rọgbọ fún wọn, ní ọ̀nà kan tí ó wù wọ́n. Nítorí náà, olúkúlùkù wa lè bi ara rẹ̀ pé, ‘Mo ha ń lo ara mi taápọntaápọn àti tìtaratìtara bí?’—6/15, ojú ìwé 31.

◻ Báwo ni a óò ṣe “ṣèdájọ́” àwọn òkú tí a jí dìde “láti inú nǹkan tí a kọ sínú àwọn àkájọ ìwé náà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ wọn”? (Ìṣípayá 20:12)

Àkájọ ìwé wọ̀nyí kì í ṣe àkọsílẹ̀ ohun tí wọ́n ṣe látẹ̀yìnwá; nígbà tí wọ́n kú, a dá wọn sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ nígbà ayé wọn. (Róòmù 6:7, 23) Àmọ́ ṣá o, àwọn ènìyàn tí a jí dìde yóò ṣì wà lábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù. Nítorí náà, ó ní láti jẹ́ pé àkájọ ìwé wọ̀nyí yóò lànà àwọn ìtọ́ni àtọ̀runwá sílẹ̀, tí gbogbo ènìyàn gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé láti lè jẹ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àǹfààní láti inú ẹbọ Jésù Kristi.—7/1, ojú ìwé 22.

◻ Àwọn ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ láti inú àkàwé tí Jésù ṣe nípa oníyọ̀ọ́nú ará Samáríà náà? (Lúùkù 10:30-37)

Àkàwé Jésù fi hàn pé ẹni tí ó dúró ṣánṣán ní tòótọ́ ni ẹni tí kì í ṣe pé ó ń pa òfin Ọlọ́run mọ́ nìkan ni, ṣùgbọ́n, tí ó tún ń fara wé àwọn ànímọ́ rẹ̀. (Éfésù 5:1) Ó tún fi hàn pé ọ̀ràn orílẹ̀-èdè, àṣà ìbílẹ̀, àti ìsìn kò gbọ́dọ̀ pààlà sí bí a óò ti jẹ́ oníyọ̀ọ́nú tó. (Gálátíà 6:10)—7/1, ojú ìwé 31.

◻ Àwọn àgbègbè mẹ́ta wo ni o ti lè mọ àwọn ọmọ rẹ, kí o sì tọ́ wọn sọ́nà gẹ́gẹ́ bí òbí?

(1) Ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti yan iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tó dára; (2) múra wọn sílẹ̀ láti lè kojú másùnmáwo nílé ìwé àti níbi iṣẹ́; (3) fi bí wọ́n ṣe lè tẹ́ àwọn àìní wọn tẹ̀mí lọ́rùn hàn wọ́n.—7/15, ojú ìwé 4.

◻ Èé ṣe tí Ọlọ́run fi sinmi ní “ọjọ́ keje”? (Jẹ́nẹ́sísì 2:1-3)

Kì í ṣe nítorí pé ó rẹ Ọlọ́run ni ó fi sinmi. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ṣíwọ́ ṣíṣe àwọn iṣẹ́ orí ilẹ̀ ayé kí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ lè fara hàn, kí wọ́n sì dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ògo, fún ìyìn àti ọlá rẹ̀.—7/15, ojú ìwé 18.

◻ Àwọn ọ̀nà mẹ́ta wo ni a lè gbà ṣe ìdájọ́ òdodo?

Èkíní, a gbọ́dọ̀ máa gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀pá ìdíwọ̀n ìwà híhù tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀ (Aísáyà 1:17) Èkejì, a ń ṣe ìdájọ́ òdodo bí a bá ń ṣe sí àwọn ẹlòmíràn bí a ti fẹ́ kí Jèhófà ṣe sí wa. (Sáàmù 130:3, 4) Ẹ̀kẹta, a ń fi ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run ṣèwà hù bí a bá jẹ́ ògbóṣáṣá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. (Òwe 3:27)—8/1, ojú ìwé 14, 15.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́