Ogun Tí Ó Fòpin Sí Ọ̀rúndún Kọkàndínlógún
1914
NÍGBÀ tí ó ń ronú lórí ẹgbẹ̀rúndún tuntun náà, Charley Reese, òǹkọ̀wé ìwé ìròyìn The Orlando Sentinel, kọ̀wé pé: “Ogun tí ó jà ní ọdún 1914 sí 1918, tí ó fòpin sí ọ̀rúndún kọkàndínlógún kò tí ì parí.” Kí ni ó ní lọ́kàn? Ó ṣàlàyé pé: “Kì í ṣe déètì ni ó ń ṣàkóso ìtàn. Ọ̀rúndún kọkàndínlógún—tí a túmọ̀ sí ọ̀wọ́ àwọn èrò ìgbàgbọ́, èròǹgbà, ìṣarasíhùwà àti ìlànà ìwà híhù—kò dópin ní Jan. 1, 1901. Ọdún 1914 ló dópin. Ìgbà yẹn gan-an ni ọ̀rúndún ogún tí a túmọ̀ lọ́nà kan náà bẹ̀rẹ̀. . . .
“Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé inú ogun yẹn ni gbogbo ìforígbárí tí a ti dojú kọ ní gbogbo sáà ìgbésí ayé wa ti wá. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo òye àti ìtẹ̀sí ìṣẹ̀dálẹ̀ tí a ní pilẹ̀ nínú ogun náà. . . .
“Mo gbà pé ó ṣe irú ọṣẹ́ bẹ́ẹ̀ nítorí pé ó pa ìgbàgbọ́ àwọn ènìyàn pé èèyàn lè ṣàkóso kádàrá rẹ̀ run. . . . Ogun náà mú kí àwọn èèyàn pa ìgbàgbọ́ wọn tì. Kò sí ẹnikẹ́ni ní ìhà méjèèjì tí ó rò pé yóò rí gẹ́gẹ́ bí ó ṣe rí. Ó pa agbára ayé Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti ti Faransé run. Ó pa ìran àwọn ọkùnrin tí ó ní láárí jù lọ run ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Faransé àti Germany. . . . Láàárín sáà díẹ̀, ó pa ènìyàn mílíọ̀nù 11.”
Fún ohun tí ó lé ní 120 ọdún báyìí, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń tọ́ka sí ọdún 1914 gẹ́gẹ́ bí òpin ohun tí Jésù pè ní “àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè.” (Lúùkù 21:24) Ní ọdún yẹn, a gbé Jésù Kristi tí a jí dìde, tí a sì ṣe lógo ka orí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba ọ̀run. Nípasẹ̀ Ìjọba yẹn, Jèhófà Ọlọ́run yóò mú gbogbo ìyà tí ń jẹ ọ̀rúndún yìí kúrò pátápátá.—Sáàmù 37:10, 11; Oníwàásù 8:9; Ìṣípayá 21:3, 4.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]
Fọ́tò U.S. National Archives