Àwọn Atọ́nà Ní Ọ̀nà Ìyè
BÍ O bá ti ń gba ọ̀nà kan tí o kò mọ̀ dáadáa lọ, ìwọ yóò ha wo àwọn àmì atọ́nà ojú ọ̀nà náà bí ìdíwọ́ bí? O lè má ṣe bẹ́ẹ̀! Dájúdájú, ìwọ yóò wò wọ́n bí ohun tí kò ní jẹ́ kí o sọnù.
Ọ̀ràn ti rírìn ní ọ̀nà ìyè wá ńkọ́? Ǹjẹ́ a lè rìn ín jálẹ̀ láìsí àwọn atọ́nà? Wòlíì Ọlọ́run kan, láyé àtijọ́, sọ bí agbára ènìyàn ṣe mọ nínú ọ̀ràn yìí. Ó wí pé: “OLÚWA, mo mọ̀ pé ènìyàn kò lè yan ọ̀nà ara rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ti ènìyàn láti darí ìṣísẹ̀ rẹ̀ nínú ìgbésí ayé.”—Jeremáyà 10:23, The New English Bible.
Nígbà náà, ibo ni a wá ti lè rí ìtọ́sọ́nà tí a nílò? Ẹlẹ́dàá ènìyàn ni orísun tí ó ṣeé gbíyè lé tí a ti lè rí irú ìtọ́sọ́nà bẹ́ẹ̀, inú Bíbélì sì ni àwọn atọ́nà ìṣàpẹẹrẹ náà wà. Jèhófà sọ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Etí rẹ yóò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ kan lẹ́yìn rẹ tí ń sọ pé: ‘Èyí ni ọ̀nà. Ẹ máa rìn nínú rẹ̀,’ bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ lọ sí apá ọ̀tún tàbí bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ lọ sí apá òsì.”—Aísáyà 30:21.
Òtítọ́ ni, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń pèsè ìtọ́sọ́nà tí ó ṣeé gbíyè lé nínú gbogbo apá ìgbésí ayé wa. (Aísáyà 48:17; 2 Tímótì 3:16, 17) Síbẹ̀síbẹ̀, ó bani nínú jẹ́ pé èyí tó pọ̀ jù lọ nínú aráyé ní ń dá tọ ọ̀nà ìyè láìtẹ̀lé ìtọ́sọ́nà àtọ̀runwá. (Mátíù 7:13) Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn atọ́nà náà kò kúrò níbi tí wọ́n wà! Ìwọ yóò ha kọbi ara sí wọn bí o ti ń tọ ọ̀nà ìyè bí?