“Àwa Kátólíìkì Ní Ọ̀pọ̀ Ẹ̀kọ́ Láti Kọ́ Lára Wọn”
OLÙKỌ́ kan ní Bari, Ítálì, ló sọ ohun tí ó kíyè sí yìí nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà tí ó ń kọ́ àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ gíga lẹ́kọ̀ọ́ ìtàn ìsìn. Olùkọ́ náà ti sọ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà pé òun yóò fún wọn ní fídíò wò fún ìsọfúnni tí ó wúlò. Nígbà tí ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà, Roberto, tí ó jẹ́ ọmọ ọdún 18, gbọ́ èyí, ó dámọ̀ràn jíjíròrò nípa ìsìn òun pẹ̀lú. Ó fún olùkọ́ náà ní fídíò Jehovah’s Witnesses—The Organization Behind the Name. Ó gbà fún Roberto, gbogbo 30 akẹ́kọ̀ọ́ tí ó wà ní kíláàsì náà sì wo fídíò náà. Roberto sọ pé: “Ìṣọ̀kan, ìṣètò, àti ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tí ó wà láàárín Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wú gbogbo wọn lórí. Ẹnu tún yà wọ́n gan-an nígbà tí wọ́n gbọ́ pé 40 mílíọ̀nù ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ àti 36 mílíọ̀nù ẹ̀dà Jí! ni a ń tẹ̀ jáde lóṣooṣù.”
Lẹ́yìn tí wọ́n wo fídíò náà tán, àwọn mélòó kan lára àwọn ọmọ kíláàsì Roberto sọ pé: “N kò ronú kàn án rí pé ẹ lè ṣe nǹkan nigín-nigín bẹ́ẹ̀yẹn.” Olùkọ́ náà sọ nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé: “Ẹ ṣàkíyèsí bí ìsìn wọn ṣe ń sún wọn wà ní ìṣọ̀kan, tí wọ́n sì wà létòlétò gan-an. Àwa Kátólíìkì ní ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ láti kọ́ lára wọn.” Fídíò tí wọ́n wò àti ìjíròrò tí wọ́n ní lẹ́yìn náà jẹ́ kí wọn lóye púpọ̀ sí i nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.