“Ẹ̀yin Lẹ̀ Ń Ṣe Bí Ọlọ́run Ṣe Fẹ́ Ká Máa Ṣe”
BÍ ÀWỌN Kristẹni bá ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn aláṣẹ ayé “nítorí Olúwa,” wọ́n lè retí ‘kí á yìn wọ́n gẹ́gẹ́ bí olùṣe rere.’ (1 Pétérù 2:13-15) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Gúúsù Áfíríkà nírìírí èyí láìpẹ́ yìí nígbà àpéjọpọ̀ àgbègbè tí wọ́n ṣe nínú gbọ̀ngàn ilé ẹ̀kọ́ gíga kan.
Ní ọjọ́ tí àpéjọpọ̀ náà bẹ̀rẹ̀, àwọn ọlọ́pàá tí ń dáàbò bo ilé ẹ̀kọ́ gíga náà dira háháhá nítorí àíbaàámọ̀ tí ìjà bá dé àti nítorí àwọn mìíràn tí wọn yóò wá síbẹ̀ tó jẹ́ pé onímọ̀dàrú ni wọ́n, bí ó ti sábà máa ń rí ní onírúurú àwọn àpéjọpọ̀ mìíràn. Níwọ̀n bí wọn kò ti ní àjọṣe pẹ̀lú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí, kò sí àní-àní pé ìyàlẹ́nu ńlá ni èyí máa jẹ́ fún wọn!
Gẹ́gẹ́ bí apá kan iṣẹ́ ẹ̀ṣọ́ tí wọ́n ń ṣe lẹ́nu géètì, àwọn ọlọ́pàá aláàbò yẹ gbogbo ọkọ̀ tí ń wọnú ọgbà àti èyí tí ń jáde wò. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àyẹ̀wò náà fa ìdádúró fún àwọn tó wá ṣèpàdé, kàyéfì ńlá ló jẹ́ fún àwọn ọlọ́pàá náà bí wọ́n ṣe ń fi ọ̀yàyà kí wọn, tí wọn ò kánjú, tí wọ́n sì ń fi ọ̀wọ̀ tiwọn wọ̀ wọ́n. Kò sẹ́ni tó yarí mọ́ wọn lọ́wọ́, kò sẹ́ni tó jiyàn, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹnì kan kò bú wọn, bí àwọn mìíràn ti sábà ń ṣe. Ọ̀gá aláàbò kan sọ pé: “Ẹ̀yin ò ṣe bí àwọn àlejò mìíràn ti máa ń ṣe, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìwà tútù yín tó wuyì, kò pamọ́ fún ẹnikẹ́ni.”
Gbàrà tí ọ̀gá àgbà àwọn aláàbò náà ti kíyè sí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ó pinnu pé, kò pọndandan láti máa yẹ inú ọkọ̀ wò mọ́, ó sọ pé: “Nítorí ọmọlúwàbí ni yín.” Nítorí náà, gbogbo ọkọ̀ tí a lẹ “JW” mọ́ (ìgékúrú orúkọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lédè Gẹ̀ẹ́sì) ni wọ́n gbà kó wọlé láìyẹ inú wọn wò.
Nígbà tí àpéjọpọ̀ náà parí, ọ̀gá àgbà àwọn aláàbò náà wí pé, òun tún ń retí Àwọn Ẹlẹ́rìí láìpẹ́. Ó sọ pé: “A kò tí ì rí irú àwọn èèyàn tó mọ̀wàá hù báyìí rí. Ẹ̀yin lẹ̀ ń ṣe bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ ká máa ṣe.” Irú ìgbóríyìn bẹ́ẹ̀ túbọ̀ jẹ́ kóríyá fún àwọn Kristẹni tòótọ́ láti ‘tọ́jú ìwà wọn,’ kí àwọn ènìyàn ‘lè yin Ọlọ́run lógo nítorí iṣẹ́ àtàtà tí wọ́n fojú rí.’—1 Pétérù 2:12.