Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn
Wíwá Ọlọ́run Tòótọ́ Mú Èrè Wá
NÍ Ọ̀RÚNDÚN kẹwàá ṣááju Sànmánì Tiwa, ìjọsìn èké kún ìjọba ẹ̀yà méjì Júdà dẹ́dẹ́ẹ́dẹ́. Ṣùgbọ́n o, nínú ìbọ̀rìṣà tó gbalégbòde yìí, ọkùnrin kan wà tí ọkàn-àyà rẹ̀ dúró ṣinṣin ti Ọlọ́run. Jèhóṣáfátì lorúkọ rẹ̀. Wòlíì Jéhù sọ nípa rẹ̀ pé: “A rí àwọn ohun rere pẹ̀lú rẹ, nítorí pé o ti . . . múra ọkàn-àyà rẹ sílẹ̀ láti wá Ọlọ́run tòótọ́.” (2 Kíróníkà 19:3) Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ lónìí, ní “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” yìí, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ti ‘múra ọkàn-àyà wọn sílẹ̀’ láti wá Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́. (2 Tímótì 3:1-5) Ìrírí táa fẹ́ sọ yìí, tó wá láti ilẹ̀ Tógò, ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà, kín èyí lẹ́yìn.
Iléèwé Kátólíìkì ni Casimir lọ, ó sì kọ́kọ́ Jẹ Ara Olúwa nígbà tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn-án. Ṣùgbọ́n nígbà tí Casimir máa pé ọmọ ọdún mẹ́rìnlá, kò lọ ṣọ́ọ̀ṣì mọ́. Èyí wá bẹ̀rẹ̀ sí já a láyà, nítorí ó gbà pé ṣíṣàì lọ síbi Ààtò Jíjẹ Ara Olúwa yóò sọ òun di èrò ọ̀run àpáàdì, tàbí ó kéré tán, èrò pọ́gátórì.
Níléèwé, Casimir wọ ẹgbẹ́ àwọn ọ̀dọ́ tí ń ṣèpàdé lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó tún bẹ̀rẹ̀ sí ka Bíbélì láyè ara ẹ̀. Nígbà kan tí Casimir ń ka ìwé Ìṣípayá, ó kà nípa àkòtagìrì ẹranko ẹhànnà kan tó jáde wá láti inú òkun. (Ìṣípayá 13:1, 2) Nígbà tó béèrè nípa èyí lọ́wọ́ aṣáájú ẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà, ó sọ fún un pé ẹranko gidi lẹranko ẹhànnà náà o, àti pé yóò jáde wá láti inú òkun ní ti gàsíkíá. Àlàyé yìí dààmú Casimir, nítorí itòsí Etíkun Àtìláńtíìkì ló ń gbé. Ó dá a lójú pé òun máa wà lára àwọn tí ẹranko ẹhànnà náà yóò kọ́kọ́ pa jẹ.
Casimir bẹ̀rẹ̀ sí tu owó jọ, ó fẹ́ sá lọ sí aṣálẹ̀ níhà àríwá, kò fẹ́ kí ẹranko ẹhànnà náà pa òun jẹ. Ó sọ fún ọmọ kíláàsì rẹ̀ kan nípa bóun ṣe fẹ́ rìn ín. Ọmọ kíláàsì rẹ̀ ọ̀hún, tó jẹ́ ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, fi yé e pé kò sírú ẹranko ẹhànnà gidi bẹ́ẹ̀ tí yóò jáde wá láti inú òkun. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni wọ́n pe Casimir pé kó ká lọ sípàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ó gbádùn ìpàdé náà gan-an, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lọ déédéé. Ó tún tẹ́wọ́ gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé.
Bí Casimir ti ń tẹ̀ síwájú nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, ni ìdílé bá gbógun tì í. Àwọn baba ńlá ni ìdílé yìí ń bọ, wọ́n sì máa ń jẹ ẹran tó kú gífà, tí wọ́n fi ṣẹbọ kù. Nígbà tí Casimir kọ̀, láìfi ṣe tìjà, tó lóun ò ní jẹ irú ẹran yẹn, wọ́n ní àfira, kó kúrò nílé àwọn. Casimir kò jà, kò ta, àwọn náà sì wá fi í lọ́rùn sílẹ̀. Ṣùgbọ́n o, oṣù mẹ́ta gbáko, ló fi jẹ́ pé irú ẹran yẹn nìkan ni wọn fi ń sebẹ̀ fún ìdílé jẹ. Casimir kò rí oúnjẹ tó tó jẹ, ṣùgbọ́n ó fara da èyí, àtàwọn ìnira mìíràn.
Casimir ń tẹ̀ síwájú nìṣó nípa tẹ̀mí, títí ó fi ṣe ìyàsímímọ́ àti ìbatisí. Lẹ́yìn náà, ó di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, ó sì lọ sí kíláàsì kẹrin ti Ilé Ẹ̀kọ́ Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́, ní Tógò. Ní bí a ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí, ó ń gbádùn iṣẹ́ ìyọ̀ǹda ara ẹni ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ ní Tógò.
Bẹ́ẹ̀ ni o, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà la ti rí i pé òtítọ́ lọ̀rọ̀ Ọba Dáfídì, pé: “Bí ìwọ bá wá [Jèhófà], yóò jẹ́ kí o rí òun.”—1 Kíróníkà 28:9.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Casimir (lápá ọ̀tún) ń gbádùn iṣẹ́ ìyọ̀ǹda ara ẹni ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ ní Tógò