ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 2/1 ojú ìwé 24
  • Erékùṣù Kékeré Tó Dá Dó

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Erékùṣù Kékeré Tó Dá Dó
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 2/1 ojú ìwé 24

Erékùṣù Kékeré Tó Dá Dó

Ọ̀RỌ̀ àpèjúwe táa sábà máa fi ń ṣàpèjúwe erékùṣù St. Helena ni “dá dó” àti “kékeré.” Ó sì bá a mu, torí pé erékùṣù yìí, tí gígùn rẹ̀ jẹ́ kìlómítà mẹ́tàdínlógún, tí fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ kìlómítà mẹ́wàá, jẹ́ ẹgbàá ó dín àádọ́ta [1,950] kìlómítà sí ilẹ̀ tó sún mọ́ ọn jù lọ, ìyẹn, etíkun ìwọ̀ oòrùn gúúsù Áfíríkà. Ibí yìí ni ìgbèkùn tí wọ́n rán Napoléon Bonaparte lọ lọ́dún 1815, lẹ́yìn tí wọ́n ṣẹ́gun rẹ̀, erékùṣù yìí ló sì ti lo ìyókù ayé ẹ̀.

Béèyàn ba ń wo erékùṣù yìí láti ojú òkun, ṣe ló dà bí odi agbára tó dúró wandi. Ní ti gidi, erékùṣù yìí jẹ́ ilẹ̀ tó ru jáde láti inú òkun Àtìláńtíìkì, ó sì ní àwọn òkè tó ga tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta sí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin mítà. Àárín gbùngbùn rẹ̀ ni Òkè Actaeon wà, òkè yìí tó ga ní ẹgbẹ̀rin lé méjìdínlógún [818] mítà, ló ga jù ní gbogbo erékùṣù náà. Nítorí atẹ́gùn títutù láti Gúúsù Àtìláńtíìkì àti ìgbì òkun, ipò ojú ọjọ́ ní erékùṣù náà sábà máa ń tutù pẹ̀sẹ̀, ó sì máa ń tuni lára. Ṣùgbọ́n o, láti ẹ̀bá etíkun nísàlẹ̀ títí dé àárín gbùngbùn tí ó ní òkè ńláńlá, ipò ojú ọjọ́ kò dúró sójú kan, ilẹ̀ wọn sì yàtọ̀ síra.

Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ló ni St. Helena láti apá ìparí ọ̀rúndún kẹtàdínlógún. Nǹkan bíi ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [5,000] èèyàn tí ń gbé erékùṣù yìí jẹ́ àdàpọ̀ àwọn èèyàn tó ṣẹ̀ wá láti ilẹ̀ Yúróòpù, Éṣíà, àti Áfíríkà. Èdè Gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n ń sọ jákèjádò erékùṣù yìí, ṣùgbọ́n ọ̀nà tí wọ́n gbà ń sọ tiwọn tún yàtọ̀ díẹ̀. Kò sí pápákọ̀ òfuurufú níbí o; ọkọ̀ òkun nìkan lèèyàn lè bá débí, ibi tí ó máa ń gbà wá ni Gúúsù Áfíríkà àti England. Àní, nǹkan bí ọdún 1995 ni iléeṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n ṣẹ̀ṣẹ̀ débí, ọpẹ́lọpẹ́ ẹ̀rọ sátẹ́láìtì.

Lọ́dún díẹ̀ lẹ́yìn 1930 ni ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run kọ́kọ́ dé èbúté erékùṣù yìí. (Mátíù 24:14) Láti ọdún wọ̀nyẹn títí di ìsinsìnyí, ọ̀pọ̀ àwọn ará erékùṣù ti nawọ́ gán ìṣúra yìí tí ń sọ ọrọ̀ ti ara di yẹpẹrẹ. (Mátíù 6:19, 20) Lónìí o, ní ti ìpíndọ́gba iye Àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà nílùú, St. Helena ló gbapò iwájú, ó ní ìpíndọ́gba Ẹlẹ́rìí kọ̀ọ̀kan fún mọ́kànlélọ́gbọ̀n aráàlú, kò sírú ẹ̀ lágbàáyé!

[Àwọn àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 24]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

St. Helena

JAMESTOWN

Levelwood

ÁFÍRÍKÀ

ÒKUN ÀTÌLÁŃTÍÌKÌ

St. Helena

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́