“Tọ́ Ọmọdékùnrin”
IṢẸ́ ọ̀gbìn tó múná dóko kì í kàn-án ṣe ọ̀ràn wíwulẹ̀ fọ́n irúgbìn sílẹ̀, ká wá padà wá lẹ́yìn oṣù díẹ̀ láti wá kórè. Iṣẹ́ àṣekára gidi ń bẹ nínú dídáko, fífúnrúgbìn, àti bíbomirin àti títọ́jú àwọn irúgbìn náà kí wọ́n bàa lè sèso.
Iṣẹ́ wọ̀nyí fi hàn pé òtítọ́ gidi lọ̀rọ̀ inú Òwe 22:6, tó sọ pé: “Tọ́ ọmọdékùnrin ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí yóò tọ̀; nígbà tí ó bá dàgbà pàápàá, kì yóò yà kúrò nínú rẹ̀.” Ní tòótọ́, ẹ̀kọ́ látọ̀dọ̀ òbí ṣe kókó nínú títọ́mọ ní àtọ́yanjú.
Ṣùgbọ́n o, láyé òde òní táwọn èèyàn gbàgbàkugbà, ọ̀pọ̀ òbí ni kò kọbi ara sí ìmọ̀ràn yìí. Nígbà tí wọ́n bá tẹ̀ lé ọgbọ́n ayé, tó sọ pé àwọn ọmọ gbọ́dọ̀ kọ́ láti fọwọ́ ara wọn yanjú ìṣòro ara wọn, ṣe ni wọ́n sábà máa ń fi ọmọ wọn sílẹ̀ láti dá ẹrù ara wọn gbé. Irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ máa ń jẹ́ kí àwọn ọmọdé dojú kọ ewu kíkọ́ ìwà burúkú látọ̀dọ̀ àwọn kọ̀lọ̀rànsí àti kàràǹbàní ẹ̀dá.—Òwe 13:20.
Àbí ẹ ò rí bó ṣe dára tó kí àwọn òbí gbin àwọn ìlànà Kristẹni sí àwọn ọmọ wọn lọ́kàn nípasẹ̀ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà ti Ọlọ́run, láti àárọ̀ ọjọ́! Nígbà wo ní àárọ̀ ọjọ́? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Láti ìgbà ọmọdé jòjòló.” Ìgbà yẹn ni ti Tímótì ọ̀dọ́kùnrin náà bẹ̀rẹ̀. Yùníìsì, ìyá rẹ̀, àti Lọ́ìsì, ìyá rẹ̀ àgbà, gbin “ìwé mímọ́” sí Tímótì lọ́kàn, ó ‘kẹ́kọ̀ọ́,’ a sì ‘yí i lérò padà láti gbà gbọ́.’ Kí ni ìyọrísí rẹ̀? Irú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ kó ipa pàtàkì nínú sísọ ọ́ di “ọlọ́gbọ́n fún ìgbàlà.”—2 Tímótì 1:5; 3:14, 15.
Bákan náà lónìí, àwọn òbí tí kò bá “juwọ́ sílẹ̀ ní ṣíṣe ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀,” yóò ká èrè jìngbìnnì bí wọn “kò bá ṣàárẹ̀.” (Gálátíà 6:9) Sólómọ́nì Ọlọgbọ́n Ọba sọ pé: “Baba olódodo yóò kún fún ìdùnnú láìsí àní-àní.”—Òwe 23:24.