“Mo Rí I Pé Àlàáfíà Ló Jọba Níbẹ̀”
AỌKÙNRIN kan tí ń sọ èdè German lọ sí àpéjọpọ̀ tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣètò, nítorí kí ó lè “ṣamí” Àwọn Ẹlẹ́rìí. Èé ṣe? Ète rẹ̀ ni láti “táṣìírí ẹ̀ya ẹ̀sìn yìí, kí ó máà sì jẹ́ kí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ṣáko lọ.” Lẹ́yìn tó ti àpéjọpọ̀ náà dé, lẹ́tà tó kọ sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ rèé:
“Nígbà tí mo dé àgbègbè àpéjọpọ̀ náà, ṣe ni mo rò pé mo ṣìnà. N kò rí ẹnikẹ́ni níta pápá ìṣeré náà, kò sì sí bébà tàbí agolo bíà nílẹ̀. Nígbà tí mo túbọ̀ sún mọ́ ibẹ̀, mo rí àwọn ọkùnrin méjì lẹ́nu ọ̀nà pápá ìṣeré náà. Wọ́n kí mi, wọ́n sì ní kí n wọlé.
“Ariwo yèè ni mo rò pé n óò máa gbọ́ tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tó bá wà níbẹ̀ yóò máa pa, àmọ́, ṣe ni gbogbo ibẹ̀ pa rọ́rọ́. Mo wá ronú pé, ‘Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìwọ̀nba èèyàn táṣẹ́rẹ́ ló jókòó gátagàta síbẹ̀.’
“Nígbà tí mo wọlé, àwòkẹ́kọ̀ọ́ tó ń lọ lọ́wọ́ lórí pèpéle ló gba àfiyèsí mi kíá. Ẹ̀yìn ìgbà náà ni mo tó wá mọ̀ pé pápá ìṣeré náà kún fọ́fọ́ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tó tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́. Mo rí i pé àlàáfíà ló jọba níbẹ̀. Ohun tí mo gbọ́, tí mo rí, tí mo sì nímọ̀lára rẹ̀ lẹ́nu ráńpẹ́ tó kù kí àpéjọpọ̀ náà parí mà wọ̀ mí lọ́kàn o.
“Bí mo ti ń lọ tí mò ń bọ̀ láàárín Àwọn Ẹlẹ́rìí, ayọ̀ tó hàn lójú wọn àti ọ̀rọ̀ tó fi ìfẹ́ hàn tí ń jáde lẹ́nu wọn ló gbà mí lọ́kàn. Lójijì, n kò mọ ìgbà tí mo sọ ọ́ jáde pé, ‘Ká sòótọ́, àwọn èèyàn Ọlọ́run nìyí!’”
Dípò tí ‘kò fi ní jẹ́ kí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ṣáko lọ,’ ọ̀dọ́mọkùnrin náà rọ̀ wọ́n láti wá máa bá òun kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kí ló wá yọrí sí? Lónìí, ó jẹ́ Kristẹni alàgbà. Òun àti ìdílé rẹ̀ jẹ́ ògbóṣáṣá ní ọ̀kan nínú àwọn ìjọ ní Zug, Switzerland.