Ọjọ́ Tó Yẹ Ká Máa Rántí
Ní alẹ́ tó ṣáájú ọjọ́ tí Jésù kú, ó fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ní ìṣù búrẹ́dì aláìwú àti ife wáìnì kan, ó ní kí wọ́n jẹ, kí wọ́n sì mu. Ó tún sọ fún wọn pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”—Lúùkù 22:19.
Lọ́dún yìí, ọjọ́ Thursday, April 1, ni ayẹyẹ yìí bọ́ sí, ìyẹn lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà káàkiri àgbáyé yóò pé jọ ní alẹ́ àrà ọ̀tọ̀ yìí láti ṣayẹyẹ Ìṣe Ìrántí lọ́nà tí Jésù gbà pa á láṣẹ. A fi tayọ̀tayọ̀ ké sí ọ láti wá bá wa pé. Jọ̀wọ́ béèrè àkókò náà gan-an tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ yóò ṣe àkànṣe ìpàdé yìí lọ́wọ́ wọn, àti ibi tí wọn yóò ti ṣe é.