ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 4/1 ojú ìwé 32
  • Àwọn Aláṣẹ Gbóríyìn fún Àwọn Ẹlẹ́rìí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Aláṣẹ Gbóríyìn fún Àwọn Ẹlẹ́rìí
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 4/1 ojú ìwé 32

Àwọn Aláṣẹ Gbóríyìn fún Àwọn Ẹlẹ́rìí

DOÑA Teófila Martínez, tí í ṣe olórí ìlú Cádiz, lórílẹ̀-èdè Sípéènì, ìlú ńlá tó ní ibùdókọ̀ ojú omi, tó jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] kìlómítà níhà gúúsù ìwọ̀ oòrùn ìlú Madrid, gbé àmì ẹ̀yẹ kan (tí àwòrán rẹ̀ wà lókè yìí) fún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó kà pé: “Àwọn aláṣẹ ìlú Cádiz gbé àmì ẹ̀yẹ yìí fún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti fi dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àti ìsapá wọn fún ire ìlú yìí.” Kí ni Àwọn Ẹlẹ́rìí ṣe tí a fi yẹ́ wọn sí tó báyìí?

A gbé e fún Àwọn Ẹlẹ́rìí nítorí iṣẹ́ takuntakun tí wọ́n ti ṣe láti tún apá kan ibi eré ìdárayá ìlú náà ṣe. Fún ọ̀pọ̀ òpin ọ̀sẹ̀ ni ọgọ́rọ̀ọ̀rún Àwọn Ẹlẹ́rìí fi yọ̀ǹda ara wọn láti bá wọn ṣàtúnṣe àwọn ilé ìtura tó wà ní àgbékà àkọ́kọ́ ní pápá eré ìdárayá bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá ti Carranza. Ní báyìí o, gbogbo àwọn tí ń lo ibi eré ìdárayá náà ló ń gbádùn àwọn páìpù omi táa tún ṣe, àti ilẹ̀ táa tún rẹ́.

Kì í ṣòní, kì í ṣàná, ni àjọṣe tó dán mọ́rán ti wà láàárín Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti ìlú Cádiz. Ọdọọdún làwọn aláṣẹ ìlú máa ń fi inú rere yọ̀ǹda Ibi Eré Ìdárayá Carranza fún Àwọn Ẹlẹ́rìí, kí wọ́n lè lò ó fún àpéjọpọ̀ àgbègbè tí wọ́n ń ṣe lẹ́ẹ̀kan lọ́dún. Fún ìdí yìí, inú Àwọn Ẹlẹ́rìí máa ń dùn láti ṣe ohun tí wọ́n bá lè ṣe láti rí i pé ibi eré ìdárayá náà tún dára ju bí àwọn ṣe bá a.

Àmọ́ ṣá o, ní àfikún sí iṣẹ́ àṣelàágùn tí wọ́n máa ń ṣe lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan yìí, ìgbà gbogbo ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń bẹ àwọn aráàlú wò, láti ti ìlú náà lẹ́yìn lọ́nà mìíràn. Wọ́n ń pòkìkí “ìhìn rere” Ìjọba Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n o, kì í ṣe kí èèyàn lè gbóríyìn fún wọn ni wọ́n fi ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìtagbangba yìí. Wọ́n ń ṣe é ní ìgbọràn sí àṣẹ Jésù pé kí wọ́n máa wàásù “ìhìn rere ìjọba yìí,” kí wọ́n sì “máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.” (Mátíù 24:14; 28:19) Lọ́nà yìí, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣiṣẹ́ sin ìlú nípa kíkọ́ àwọn èèyàn ní “ipa ọ̀nà òdodo.”—Òwe 12:28.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́